Eyi lohun tawọn ẹbi Mohbad gbọdọ ṣe ki n too le gba lati ṣayẹwo ẹjẹ fun ọmọ mi- Iyawo oloogbe

Faith Adebọla

Yooba bọ, wọn ni, b’ina o ba tan laṣọ, ẹjẹ ki i tan leeekanna, bẹẹ lọrọ awuyewuye nipa iku gbajugbaja ọdọmọde onkọrin hipọọpu nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan tun mọ si Mohbad, pẹlu bi ọkan-o-jọkan ọrọ, itahun-sira-ẹni ati iṣọrọ-nigbesi ṣe n waye laarin baba oloogbe, Alagba Joseph Alọba, ati iyawo oloogbe, Ọmọwunmi.

Ni bayii, ọrọ ti wọn jọ n ṣe fa-n-fa le lori ni ti ayẹwo ẹjẹ ti Baba Mohbad ni o pọn dandan ki wọn ṣe fun ọmọọmọ oun ti Wunmi gbe dani, lati fidi ootọ mulẹ pe Mohbad lo lọmọ ọhun. Alagba Alọba ti sọ pe ayẹwo naa gbọdọ waye nibi meji, oun ko si gbọdọ wa ninu okunkun nipa rẹ, ati pe o digba ti ayẹwo ẹjẹ naa ba waye ki oun too gba ki wọn sinku Mohbad, lai fi ti gbajare ti Iya Mohbad ke laipẹ yii pe. O si rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu kari aye pe ki wọn ṣeranwọ owo foun lati ṣayẹwo ọhun.

Amọ, Wunmi, iyawo Mohbad ti fesi, o loun ko lodi si ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ, ṣugbọn o lawọn alakalẹ ati gbedeke ti baba ọkọ oun gbọdọ tẹle ki oun too le fara mọ ayẹwo ẹjẹ ṣiṣe fun Liam, ọmọ Mohbam.

Iyabọ Ojo, gbajumọ oṣerebinrin onitiata ilẹ wa to tun n ṣiṣẹ ajafẹtọọ ọmọniyan, to si ti wa lẹnu ọrọ yii latigba ti iku Mohbad ti waye lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lo na esi tiyawo Mohbad fun baba ọkọ rẹ ọhun sori sori ayelujara lopin ọsẹ yii.

Lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila yii, n’Iyabọ sọrọ lori ibi ti nnkan de duro lori ọrọ iku Mohbad, o si ṣalaye pe lọọya awọn mejeeji ti kọwe si ara wọn, ti baba Bohbad ti kọwe si Wunmi, lati sọ fun un nipa ayẹwo ẹjẹ, tori Wunmi ti sọ lọsẹ to ṣaaju pe ko ti i sẹnikẹni to ba oun sọrọ lori ayẹwo ẹjẹ kankan. Amọ ni bayii, wọn ti sọ ọ fun un, oun naa si ti fesi pada nipasẹ lọọya rẹ. Iyawo Mohbad sọ pe dipo meji, ọna mẹta loun maa fara mọ ki wọn ti ṣe ayẹwo ẹjẹ naa, ọkan ninu rẹ si gbọdọ waye lorileede Amẹrika, ati pe Baba Mohbad to beere fun ayẹwo ọhun lo gbọdọ gbe gbogbo inawo idi rẹ patapata.

Ẹnikan beere lọwọ Iyabọ Ojo pe ṣe ọmọ Mohbad ti wọn fẹẹ ṣayẹwo fun ti niwee-aṣẹ irinna tẹlẹ ni, abi lara inawo ayẹwo ni eyi naa maa wa, niṣe n’Iyabọ Ojo bu sẹrin-in, o ni oun ko ro pe ọmọ naa ni pasipọọtu tabi fisa tẹlẹ o, wọn ṣẹṣẹ maa gba iyẹn naa fun un ni.

Bakan naa ni Iya Liam sọ fun baba ọkọ rẹ pe oun gbọdọ ri iwe-aṣẹ lati ile-ẹjọ, ti wọn fọwọ si i pe ki ayẹwo ẹjẹ waye, koun too gba.

Wọn ni ibi ti ọrọ ọhun ṣi ta koko si dasiko yii niyẹn.

Leave a Reply