Eyi lohun tawọn Musulumi sọ nipa Arẹgbẹṣọla l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Imaamu agba ilu Oṣogbo, Sheik Musa Animashaun, ti ke si awọn oloṣelu lati ṣawokọṣe awọn iwa minisita fun ọrọ abẹle lorileede yii, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla.

Animashaun ṣalaye pe Arẹgbẹṣọla dari ipinlẹ Ọṣun pẹlu ibẹru Ọlọrun lasiko to fi jẹ gomina, o si ṣa ipa rẹ fun igbaye-gbadun awọn araalu.

Nigba to n waasu nibi irun Jumat to waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, iyẹn ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, eleyii to wa lara eto idupẹ pataki kan ti awọn ọrẹ Arẹgbẹsọla ṣe lati ki i kaabọ pada sipinlẹ Ọṣun lo ti sọrọ yii.

O ṣapejuwe Arẹgbẹ bii ọmolẹyin Allah tootọ, o gboriyin fun un fun oniruuru idagbasoke to mu ba ẹsin Islam niluu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun ati orileede Naijiria lapapọ.

Animashaun ke si awọn oloṣelu lati lo ipo wọn fun iṣẹ isin Ọlọrun ati itẹsiwaju ọmọniyan nitori eleyii nikan ni yoo mu wọn yẹ lọjọ idajọ.

Gẹge bo ṣe wi, “Gẹgẹ bii gomina, o wa pelu wa, o ṣoju awa Musulumi daadaa pẹlu bo ṣe mu idagbasoke ba ipinlẹ Ọṣun, to si tun tẹsiwaju ninu eleyii lasiko to jẹ minisita.

“A dupẹ lọwọ Allah fun igbe aye rẹ. Lati wa ni ipo adari ki i ṣe eremọde rara. O ti bori oniruuru ipenija, o si ti ṣaṣeyọri ni gbogbo ipo to ti di mu, iru rẹ ṣọwọn pupọ”

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla dupẹ lọwọ awọn Musulumi fun ifọwọsowọpọ wọn, o si ṣeleri lati tubọ maa wa ire ilu Oṣogbo ati ti ipinlẹ Ọṣun lapapọ.

Minisita tẹlẹ yii rọ wọn lati maa gbe pẹlu suuru ati alaafia nigba gbogbo. O ni Ọlọrun ti ṣeleri ọpọlọpọ nnkan meremere fun ẹnikẹni to ba ni suuru, to si duro ti I.

 

Leave a Reply