Jọkẹ Amọri
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni inu oṣerebinirin ilẹ wa to lomi lara daadaa nni, Temidayọ Amusa, ti gbogbo eeyan mọ si Dewumi Ibẹru, ṣi n dun, to n jo, to n yọ, to si n fọpẹ fun Ọlọrun Ọba fun oore ọmọkunrin ti Olọrun fi ta a lọre.
Ọjọ Iṣegun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu yii, ni wọn sọ ọmọ naa lorukọ. Ṣugbọn lẹyin isọmọlorukọ ọhun ni Dayọ gba ori ayelujara lọ, to si bẹrẹ si i fun awọn to n beere baba ọmọ rẹ lesi. Ṣe gbara ti oṣere yii ti bimọ lawọn kan ti n gbe e pooyi ẹnu, ti wọn si n beere pe ta ni baba baby, ta ni Dayọ Amusa bimọ fun. Wọn niko gbe baba ọmọ sita kawọn ri i.
Ni bayii, Dayọ Amusa ti da awọn eke adugbo to n gbe ọrọ yii kiri, ti wọn si n beere ibeere ti ko kan wọn nipa baba ọmọ rẹ lohun o.
Oṣere yii ni ṣe ọkọ tiwọn sọnu ni, o ni ṣe wọn ka sẹnsọ awọn ọkọ, wọn waa sọ pe ọkọ rẹ n kọ, o wa ninu kula yara oun ni wọn fi n beere pe ọkọ oun nkọ, abi ta ni oun bimọ fun.
Dayọ ni ọmọ ki i ṣe eeso to n ja bọ lori igi, imisi kan lo maa da pọ mọ imisi mi-in ki ọmọ too de. Oṣere yii ni oun loun jẹ oṣere ti oun jẹ ilu-mọ-ọn-ka, ti oun n ṣe fiimu, o ni oun ko waa fi ọkọ oun ṣe tiata o.
Dayọ fi kun un pe awọn nnkan kan wa ti oun ti pinnu pe oun ko ni i sọ jade, o ni ohun ti oun ba fẹẹ sọ sita nikan loun maa sọ sita. Oṣere yii ni oun fẹ alaafia, oun si fẹẹ gbadun alafia oun. Idi niyi to fi jẹ pe oun ti wọn n beere nipa igbesi aye oun ati ọkọ oun yẹn, wọn ko le ri i.
Dayọ ni oun ko le jẹ ki ẹnikẹni waa da yẹẹpẹ si gaari oun, nitori ọpọ awọn mi-in, nibi ti alayọ ba ti n yọ ayọ, ni wọn maa n wa ọna ti wọn yoo fi ba ayọ naa jẹ mọ ọn lọwọ.
Nigba to n sọrọ lori ikọmọ ọmọ rẹ tuntun yii, ọmọbinrin naa ni awọn ṣẹṣẹ maa mu ọjọ iṣọmọlorukọ ni. O ni eyi ti awọn ṣe yii, awọn to sun mọ oun bii iṣán ọrun, ti wọn ṣatilẹyin foun, ti wọn n gbadura foun, ti wọn si ti n foju sọna pe ki oun ti bi ọmọ naa ṣaaju akoko yii nikan ni awọn ko ara awọn jọ fun isọmọlorukọ naa. O ni laipẹ yii ni awọn yoo pe gbogbo eeyan nigba tawọn ba fẹẹ ṣe ikomọ, tawọn yoo si pa titi laro.
Lara awọn orukọ ti oṣere naa sọ ọmọ tuntun to ṣẹṣẹ bi ọhun ni: Ọlasunkanmi, Oluwafirewami Oluwaṣeun, Akanni, Oluwagbọtemi, Morireoluwa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Iro ati buba buluu ni Dayọ Amusa ko si lọjọ isọmọlorukọ naa, to si fi iborun le e. Bi awọn alaafaa ṣe n kọrin lo n jo, ti ayọ lọpọlọpọ si han loju rẹ bo ṣe n ki awọn alejo to wa sibi isọmọlorukọ naa.