Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kede pe ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila yii, lati bẹrẹ sisan owo-oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ naa.
Nibi eto kan ti awọn aṣoju ijọba atawọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ ti buwọ lu iwe adehun imuṣẹ owo oṣu tuntun naa nijọba ti sọ pe owo-oṣu tuntun naa yoo tun fara han ninu owo-oṣu kọkanla ti awọn oṣiṣẹ yoo gba.
Bakan naa nijọba kede pe oun yoo ṣafikun ẹgbẹrun lọna mẹẹẹdọgbọn Naira sori owo ajẹmọnu oṣooṣu ti gbogbo awọn oṣiṣẹ-fẹyinti n gba.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ diẹ sẹyin ni Gomina Ademọla Adeleke kede pe ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin Naira ni yoo jẹ owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ nipinlẹ Ọṣun.
O ni bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹrun lọna aadọrin gan-an ni gbedeke tijọba apapọ gbe kalẹ, sibẹ, gẹgẹ bii ijọba to ni imọlara ilakọja awọn araalu, oun gbe owo ti Ọṣun si ẹgbẹrun lọna marundinlọgọrin.
Nigba ti aṣoju awọn oṣiṣẹ bii Nigeria Labour Congress, Trade Union Congress, JNC, awọn oṣiṣẹfẹyinti, ati bẹẹ bẹẹ lọ ka akọsilẹ adehun naa tan nibi eto to waye ninu ọfiisi gomina ni Àbere, ni wọn buwọ lu u.
Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ijọba, Comrade Christopher Arápáṣòpó, gboṣuba fun Gomina Adeleke pe o ṣeleri, o si ṣe bẹẹ gẹgẹ.
O ni igba akọkọ niyi ninu itan ipinlẹ Ọṣun ti gomina yoo ba awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣeleri, ti ko si ni i yi ohunkohun pada ninu ẹ.
Arapaṣopo waa fi da gomina loju pe gbọningbọnin lawọn oṣiṣẹ wa pẹlu rẹ, bẹẹ ni ko si eyi ti yoo ṣe imẹlẹ lẹnu iṣẹ rẹ laarin awọn.
Ninu sọrọ tiẹ, Igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọmọọba Kọla Adewusi, sọ pe lẹyin ọpọlọpọ ifikunlukun nijọba pinnu pe labẹ bo ti wu ko ri, igbaye-gbadun awọn oṣiṣẹ ni akọkọ.
O ke si awọn oṣiṣẹ pe ni bayii ti awo ijọba Adeleke ti ki fun wọn, ki awọn naa ki fun awo pada nipa ṣiṣe atilẹyin funjọba to wa lode bayii.