Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adeṣọla Adedeji to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileetura Hilton, niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti OAU nni, Timothy Adegoke, ku si loṣu Kọkanla, ọdun to kọja, ti sọ pe oun ko gbimọ-pọ pẹlu ẹnikẹni lati pa oloogbe.
Nigba to n wi awijare rẹ niwaju adajọ ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, lo ṣalaye pe aago mejila ọsan ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla, ọdun 2021, loun wọ iṣẹ, ko si si alejo kankan to wa si otẹẹli titi di nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ.
O ni nigba ti aago mẹfa irọlẹ ku diẹ ni alejo ọkunrin kan de, o si sọ pe oun yoo gba yara ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun aabọ Naira fun ọjọ meji.
Adeṣọla fi kun ọrọ rẹ pe, “Mo pe Manija, Oyetunde Kazeem, pe ko wa si isalẹ, mo si ko kọkọrọ awọn yara to jẹ iye owo yẹn fun un, awọn mejeeji jọ lọ si oke, nigba ti awọn mejeeji pada sisalẹ ni manija sọ fun mi pe alejo yẹn ti mu yara to ni nọmba 305.
“Mo beere lọwọ alejo yẹn pe bawo lo ṣe fẹẹ sanwo, o si sọ fun mi pe oun ko ni Naira lọwọ, ṣe loun fẹẹ ṣe tiransifaa, mo pe manija lori foonu pe ko pada wa si risẹpṣan (reception) ti mo wa lati ṣalaye fun un nitori alejo akọkọ ti a maa ni lọjọ yẹn ni, a si nilo lati ra awọn nnkan kan si otẹẹli.
“Manija mọ pe alejo yii sanwo sinu akanti mi lati le fi ra awọn nnkan bii disu atawọn atunṣe kekeke kan. Ọkunrin yii san ẹgbẹrun lọna mẹtadinlogoji sinu akanti mi, mo si fun manija ni ATM mi lati gba owo yẹn lati le fi ra diisu.
“Lẹyin ti ọkunrin yii, alejo mẹẹẹdogun miiran ni mo tun gba sinu otẹẹli lalẹ ọjọ yẹn, gbogbo wọn si jẹ mẹrindinlogun. Laarin aago mọkanla si mejila oru ni mo palẹ iwe akọsilẹ mọ loju manija, mo si fi foonu mi ya awọn akọsilẹ ti mo ṣe lọjọ naa. Aago marun-un aabọ idaji ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ni Ọgbẹni Oluwọle Lawrence de lati yẹ awọn yara ti a ko gbalejo si wo, a si jọ ka wọn, lẹyin naa lo buwọ lu akọsilẹ mi, to si sọ pe ohun gbogbo lọ daradara.
“Laago mẹjọ aarọ, manija sọ fun mi pe oun n lọ si irinajo, mo si wa nibẹ titi di aago mejila ọsan ti Magdalene de sibi iṣẹ. Mo ṣalaye fun un pe awọn alejo meji ṣi wa ninu yara wọn ti wọn ti sanwo ọjọ meji. Lẹyin gbogbo eleyii ni mo rinrin-ajo lọ siluu Ileṣa.
“Lọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla, Esther Ashigo pe mi lori foonu pe ipade kan wa nile alaga wa ni Parakin, mo sọ fun un pe n ko le raaye wa nitori n ko si n’Ileefẹ. Nigba to tun di aago mẹjọ aabọ ni Quadri naa tun pe mi lori ipade yẹn, bayii ni mo fori le Parakin.”
Adeṣọla sọ siwaju pe nigba toun debẹ, oun ti ba awọn oṣiṣẹ kan nibẹ, Raheem Adedoyin si mu oun lọ sinu ile miiran to wa ninu ọgba wọn, o fun oun ni risiiti ati iwe akọsilẹ kan ti wọn ko kọ nnkan kan si pẹlu nọmba 7316 pe ki oun bu ọwọ lu u, o ni nigba ti oun beere idi ẹ, Raheem sọ pe aṣiṣe wa ninu akọsilẹ toun ṣe lọjọ karun-un, oṣu Kọkanla ni.
O ni nigba to di pe awọn ọlọpaa mu awọn, ti wọn fi akọsilẹ ọjọ iṣẹlẹ naa han oun, loun ri i pe orukọ alejo to jẹ nọmba 1 ko si nibẹ mọ, ati pe ki i ṣe iwe akọsilẹ toun buwọ lu lọjọ naa lo wa lọdọ awọn ọlọpaa.
Lẹyin ti awọn agbẹjọro olujẹjọ yooku ati agbẹjọro olupẹjọ, iyẹn Fẹmi Falana, fọrọ wa a lẹnu wo ni gbogbo wọn fẹnu ko lati sun igbẹjọ siwaju di ọjọ keji, oṣu Keji, ọdun 2023.