Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Aarẹ tẹlẹ ri lorileede Naijiria, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti sọ pe pẹlu awọn awodami-ẹnu iṣẹ akanṣe to n lọ lọwọ nipinlẹ Ọṣun, ko si oludokoowo ti ko ni i fẹ lati da iṣẹ silẹ nibẹ.
Bakan naa lo tun parọwa si Gomina Ademọla Adeleke lati ma ṣe bojuwẹyin lori oniruuru igbesẹ to n gbe, eleyii to mu ki ipinlẹ Ọṣun wa lara awọn ipinlẹ ti alaafia ti n jọba ju lọ lorileede yii.
Lasiko ti Oloye Ọbasanjọ n ṣi ile nla kan tijọba Ọṣun kọ fun awọn alejo, iyẹn VIP Lodge, eleyii to wa ninu ọgba ile ijọba niluu Oṣogbo, lo ti sọ fun gomina lati ma ṣe mikan nipa awọn ti wọn n fi i ṣe yẹyẹ pe arijoyọ ni.
Ọbasanjọ ṣalaye pe ọpọlọpọ awọn eeyan ni wọn ti ro Adeleke pin pe ko si ohun rere kan tijọba rẹ le ṣe fawọn eeyan Ọṣun pẹlu bo ṣe maa n jo ni gbogbo igba, ṣugbọn iyalẹnu nla ni oniruuru iṣẹ idagbasoke to n lọ lọwọ kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii jẹ.
O ni, ‘’Pẹlu ohun ti mo ti ri laarin ọjọ mẹta ti mo ti lo nipinlẹ Ọṣun ati awọn nnkan ti mo ti gbọ, ẹnikẹni to ba tun n sọ pe ko si iṣẹ idagbasoke kankan l’Ọṣun, ẹ jẹ ki iru ẹni bẹẹ waa fi oju ara rẹ ri i.
‘Mo fẹ ki o tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ idagbasoke yii, nitori ọpọlọpọ awọn oludaṣẹsilẹ ni wọn n wa ibi ti alaafia wa, ti aaye yoo si ti gba wọn, pẹlu iṣẹ to si n lọ l’Ọṣun bayii, awọn eeyan yii yoo nifẹẹ lati ba ijọba yii ṣiṣẹ’
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Gomina Ademọla Adeleke ṣalaye pe niwọn igba ti iṣejọba jẹ ohun to n tẹsiwaju, idi niyẹn ti oun fi pinnu lati pari ilegbee awọn alejo naa.
Adeleke fi kun ọrọ rẹ pe ijọba ẹgbẹ APC kan lo bẹrẹ iṣẹ naa nipinlẹ Ọṣun, ijọba yẹn si ba a de ida marundinlogoji ninu ida ọgọrun-un.
Nigba ti ijọba ẹgbẹ APC miiran de, Adeleke ṣalaye pe iyẹn ko fọwọ kan iṣẹ ile naa rara, niwọn igba to si jẹ pe ile naa yoo wulo fun ipinlẹ Ọṣun, lai fi ti ijọba to wa lori aleefa ṣe, loun ṣe pinnu lati pari rẹ.