Eyi lohun ti oju mi ri latimọle ọlọpaa-Trinity Guy

Monisọla Saka

Gbajumọ alawada ori ẹrọ ayelujara to filu Ibadan ṣebugbe nni, ṣugbọn tọrọ oun pẹlu awọn agbofinro gba igboro kan lẹnu ọjọ mẹta yii, nitori awọn awada lile kan ṣe, to si tibẹ dero ọgba ẹwọn, Abdullahi Maruff Adisa, ti inagijẹ rẹ n jẹ Trinity Guy ti tẹwọn de, o si ti royin ohun toju ẹ ri lọhun-un.

Nigba to n sọrọ nipa gbogbo awọn nnkan toju ẹ ri lọgba ẹwọn, ọmọkunrin yii ni oun ti kọ ọpọlọpọ ẹkọ latara ẹ. Ninu fidio kan to ṣe to gbe sita lo ti sọ pe aye mi-in gbaa ni ọgba ẹwọn jẹ. O ni o to asiko kan toun ko tilẹ waa lominira kankan mọ, nigba to ya loun naa kuku gba kamu, toun si sọ ẹwa di ounjẹ ajẹsun.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, lo kọ oriṣiriṣii ọrọ idupẹ soju opo Instagram rẹ. O dupẹ lọwọ ara, ọrẹ, awọn alatilẹyin, atawọn ẹlẹgbẹ ẹ nidii iṣẹ awada ṣiṣe fun aduroti wọn ati bi wọn ṣe ṣoju, ti wọn tun ṣẹyin foun.

O ni leyii ti Ọlọrun ti ko oun yọ yii, oun ko tun tasẹ agẹrẹ si ọhun ti wọn ba ti pe lofin mọ, ati pe oun yoo maa ronu jinlẹ lori awọn ere toun yoo maa ṣe.

“Aye mi-in gbaa nibẹ yẹn. Mi o ni ominira kankan, mo jẹwa jẹwa…”. Idanikan wa laarin igba perete fi pataki ominira han mi, bẹẹ lo jẹ ki n mọ riri ifẹ mọlẹbi ati bi aisi tabi aito rẹ ṣe le daayan lori ru. Ma a gbiyanju lati tẹsiwaju ninu irinajo aye mi, ati lati ma ṣe yẹsẹ kuro loju ọna ere to wa ni ibamu pẹlu iwa ọmọluabi.

“Mo fẹẹ fi akoko yii fi ẹmi imoore mi han si gbogbo awọn ololufẹ mi kaakiri agbaye, gbogbo awọn ojugba mi ati gbogbo awọn mọlẹbi mi pata. O maa n jẹ nnkan to dun mọ ni nigba tẹ ẹ ba mọ pe awọn eeyan kan nifẹẹ yin gan-an. Ọlọrun aa bukun ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria, Ọlọrun aa bukun fun gbogbo awọn eeyan ti wọn duro ti mi”.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa, ọdun yii, nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ranṣẹ si Trinity Guy pe ko yọju sawọn, nitori ọkan ninu awọn ere awada ẹ to ti n beere nipa nnkan ọlọmọkunrin ara ẹ lọwọ ọmọdebinrin kan.

Ṣaaju igba naa ni ẹnu ti n kun un lori awọn ere awada lile to le ṣe eeyan leṣe to maa n ṣe, ṣugbọn to jẹ pe ti ọmọdebinrin ọhun lo pada ran an lọgba ẹwọn.

Lẹyin to yọju sawọn ọlọpaa tan ni wọn ti i mọle, ti wọn si wọ ọ lọ sile-ẹjọ Majisireeti kan to wa lagbegbe Iyaganku, Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, nibi ti adajọ ti ni ki wọn lọọ fi ọkunrin alawada yii si ọgba ẹwọn titi di oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Amọ wọn pada gba beeli rẹ, to si gba ominira kuro lẹwọn.

Trinity Guy ni oun ti kọgbọn gidi gan-an, oun ko si tun ṣan iru aṣọ bẹẹ ṣoro mọ. O ni lati isinyii lọ, ere to mu ọpọlọ dani, ti ko si ta ko iwa ọmọluabi loun yoo maa ṣe.

Leave a Reply