Eyi lohun ti Saidi Oṣupa sọ lasiko ikẹkọọ-gboye rẹ ni Fasiti Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo awọn ololufẹ orin Fuji kaakiri agbaye ni wọn ti n ki gbajugbaja olorin Fuji nni, Ọba Orin Saheed Oṣupa,

ku oriire fun bo ṣe kẹkọọ gbọye imọ nipa eto oṣelu ni Yunifasiti Ibadan.

Ninu eto ayẹyẹ ikẹkọọ-jade ti Fasiti Ibadan, (UI) ṣe ninu gbọngan nla International Conference Centre (ICC), to wa ninu ọgba fasiti naa l’Oṣupa, ẹni tawọn ololufẹ ẹ tun mọ si Olufimọ Akọkọ, ti gboye ninu imọ ijinlẹ nipa eto oṣelu l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla ta a wa yii.

Ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta (54), ti wọn tun n pe ni Matagbamọlẹ (1) yii lo gboye ijinlẹ ti wọn n pe ni (BSC) lẹyin to fakọ yọ laarin awọn ẹgbẹ ẹ pẹlu awọn esi idanwo to yanranti.

Laipẹ yii l’Oṣupa funra rẹ sọrọ nipa bi Ọlọrun ṣe fi imọ iwe da a lọla to.

Lasiko to n gba gbajumọ olorin Fuji nni, Alahji Muri Alabi Thunder atawọn olorin min-in to wọn ba a lalejo nile ẹ nimọran lo ti ṣalaye pe Ọlọrun a maa din oore eeyan ku nigba mi-in lati le fi iyi ati ibukun si oore naa.

O ni gẹgẹ bii apẹẹrẹ ọga oun kan fun oun ni maaki to kere si eyi to yẹ ki ẹni to mọwe bii toun gba, lẹyin naa lọga naa waa ṣalaye pe bi oun ba gba ami maaki to pọ ju lọ, awọn eeyan yoo ro pe owo loun fi ra maaki ọhun nitori bi oun ṣe jẹ olokiki eeyan lawujọ.

Nigba to n kede aṣeyọri ẹ yii fun gbogbo aye, Oṣupa kọ ọ sori ẹrọ ayelujara pe, “o ti kuro lọrọ ẹnu lasan wayi! Lonii, mo kopa ninu eto ikẹkọọgboye nileewe Fasiti Ibadan. Mo gboye ijinlẹ ninu imọ nipa eto oṣelu pẹlu iwe-ẹri to tayọ (2.1).

“Keku ile gbọ, ko sọ fun toko, kẹyẹ adan gbọ, ko royin fun òòbẹ̀, kẹ́yẹ́ kannakanna gbọ, ko sọ fun ologo, pe emi Ọba-Orin, Dokita Saheed Oṣupa Akorede ti di akẹkọọgboye ileewe fasiti bayii ni, University of Ibadan, pẹlu iwe ẹri to yanranti”.

Oṣupa jẹ okan ninu iwọnba awọn akẹkọọgboye tuntun ọhun ti ọgi agba patapata ni Fasiti Ibadan, Ọjọgbọn Kayọde Oyebọde Adebọwale, bọ lọwọ gẹgẹ bii akẹkọọ to jẹ amuyangan fun ileewe fasiti naa.

Tẹ o ba gbagbe, ni bii ọdun diẹ sẹyin ni oṣere yii gbe fọto to ya nibi ikẹkọọ wọle jade, to si fi han gbogbo aye pe oun ti dara pọ mọ awọn akẹkọọ ileewe naa lati fi imọ kun im si i. Ṣaaju akoko yii ni Oṣupa ti kọkọ lọ sileewe gbogboniṣe, nibi to ti gboye akọkọ (OND), ko too waa pada si Fasiti Ibadan to ti pari bayii.

Leave a Reply