Eyi lohun to ṣẹlẹ lasiko ti pasitọ agbala Gabriel ṣabẹwo si Kanran onitiata

Monisọla Saka

Gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa to gbajumọ fun kikopa baba olowo ninu awọn sinnima agbelewo ni bii ọdun diẹ sẹyin, Oluṣẹgun Akinrẹmi, tawọn eeyan mọ si Chief Kanran, ti sọ gbogbo adojukọ rẹ ati nnkan to sọ ọ di ẹni to n gbe ile ti ko bojumu, lasiko ti Pasitọ Gabriel, ti ijọ Agbala Gabriel, ṣabẹwo si i.

Inu ṣọọṣi ti wọn ba ọkunrin onitiata yii lo sọ pe oun pẹlu awọn mọlẹbi oun n gbe.

Ki wọn too yọju si i lo ti kọkọ sọ ọ lori ẹrọ ayelujara pe bo tilẹ jẹ pe oun pẹlu Pasitọ Gabriel ko ti i pade ri, oun gba ipe lati ọdọ Ọlọrun pe awọn yoo pade laipẹ, ti iranṣẹ Ọlọrun naa yoo si ṣe oun loore.

O kọ ọ soju opo ayelujara Facebook rẹ pe, “Mi o ti i ṣalabaapade Agbala Gabriel ri, ṣugbọn a mu mi ri i pe a maa pade laipẹ, ti yoo si ṣe mi loore, to si ṣee ṣe ki emi naa ni iranlọwọ fun un”.

O ni oun nifẹẹ ọkunrin naa, paapaa pẹlu oju aanu rẹ ati bo ṣe maa n ran awọn eeyan lọwọ.

Nigba to n fesi si ọrọ ti Kanran kọ yii, Pasitọ yii ni oun yoo mu ileri oun ṣẹ nipa yiyọju si oṣere yii.

Ile ijọsin wọn ni Pasitọ Gabriel ro pe o mu oun wa, ṣugbọn Kanran pada ṣalaye fun un pe ibi ti oun pẹlu awọn ẹbi oun n fori pamọ si lo ri yẹn.

O ni oun loun ni in, oun si tun kọ, nitori owo ara oun ati ti ijọ lo gbe ṣọọṣi naa duro. Ṣugbọn o da bii pe esi naa ko tẹ agbala Gabriel lọrun, nigba to wo gbogbo ayika naa, ati gbogbo oke aja ṣọọṣi ọhun ti gbogbo ogiri rẹ ti wu bọ silẹ tan, gbogbo faanu paapaa ko bọ si i mọ, ko si yẹ nibi ti ọmọluabi eeyan, paapaa ju lọ iru alafẹ eeyan bii Kanran yoo maa gbe. Eyi lo mu ko beere pe bawo ni ọrọ ṣe jẹ.

Kanran ni, “Ojiji naa ni gbogbo rẹ daru, ile jo, ole si ja. Mo ti gbe lagbegbe Surulere ri, bẹẹ ni mo ti gbe ni Mushin ri, nipinlẹ Eko, gẹgẹ bii ile ti mo n sanwo ẹ. Ṣugbọn awọn adigunjale ki i jẹ ki n gbadun. Oju Kanran inu fiimu ni wọn fi n wo mi. Wọn n ri mi bii baba olowo tabua, idi niyi to fi jẹ pe ọpọlọpọ igba ni wọn maa n waa ka mi mọle. Eyi to tun waa buru ju, to si da oju gbogbo ẹ de ni irinṣẹ mi to jona. Awọn irinṣẹ ti mo fi n ya fiimu to n lọ bii ẹẹdẹgbẹta miliọnu Naira (500 Million) lo jona. Ọkọ naa nkọ, wọn ti gori odo. Eyi la ṣe dero ṣọọṣi tẹ ẹ ti ba wa nibi”.

Nigba ti Pasitọ Gabriel tun beere pe ṣe ko si oluranlọwọ kankan to dide fun un latigba tọrọ naa ti bẹrẹ ni, ati pe ki ni nnkan to n fẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria. O ni, “Haa, awọn eeyan gbiyanju. Kọla Olootu gbiyanju gidigidi gan-an ni. Owo ti wọn ba mi wa nigba yẹn la fi ya fiimu mi tuntun ta a pe ni Ṣọbalaje. Ṣugbọn ko si owo ta a le fi ṣe ifilọlẹ rẹ ti owo yoo fi wọle wa lati yanju awọn nnkan mi-in.

Ni ti nnkan ti mo fẹ, mo fẹ ile o. Mọto ti ma a maa fi ṣe ẹsẹ rin, ki iṣẹ wa le gberu si i, ati ọpọlọpọ irinṣẹ fun fiimu yiya lo wu mi. Ti awọn eleyii ba ti yanju, abuṣe ti buṣe. Nibẹ naa la o ti rowo fi kọle ringindin, ka a to ri bii ọdun meloo si isinyii, ma a pe yin kẹ ẹ wa ba wa ṣile”.

Ko pẹ pupọ ti Alagba Gabriel debẹ, ko too bẹrẹ si i maa mu un kiri ayika ile naa lawọn eeyan ti n fowo ranṣẹ, lai jẹ pe wọn ti i bẹrẹ si i ba a tọrọ owo.

Lẹyin naa lo ni ki ọkunrin onitiata naa ki awọn araale atawọn ololufẹ ẹ. Laarin wakati meji, ki wọn too kuro nibẹ, ni owo tawọn eeyan da fun un ti le ni miliọnu kan Naira.

Ojo adura ni Chief Kanran bẹrẹ si i rọ le ojiṣẹ Ọlọrun to n figba gbogbo dun awọn alaini ninu yii lori. O ni Ọlọrun ko ni i fi i silẹ, yoo si tubọ maa fun un ṣe. Bẹẹ naa lo tun gbadura fun gbogbo awọn ti wọn ti fowo ranṣẹ si i ati gbogbo awọn ololufẹ ẹ pata. O ni atilẹyin nla loun ka ifẹ wọn si ni gbogbo igba toun n ṣere loju mejeeji, amọ ki wọn tun fifẹ naa han si oun lẹẹkan si i, koun le tun pada sidii iṣẹ toun fi n da wọn laraya, toun si fi n pa ọpọlọpọ idile lẹrin-in latẹyinwa.

Bakan naa ni Pasitọ Gabriel ṣeleri pe Ọlọrun yoo gba ọwọ awọn eeyan ẹ ṣe gbogbo nnkan ti Kanran beere fun. O ni laarin wakati meji lawọn eeyan ti da owo to le ni miliọnu kan Naira, ati pe awọn yoo mọ ibi ti yoo de ki ilẹ ọjọ naa too ṣu.

Bi wọn ṣe n sanwo wọle lo n kede, ti ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ si n ṣe iṣiro, lẹyin naa ni yoo sọ pe iye bayii bayii lowo to ti wa nilẹ.

Leave a Reply