Faith Adebọla
Ọmọ bibi ilu Ilobu, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Ọsun, ni Ọgagun Taoreed Abiọdun Lagbaja i ṣe. Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 1968, lo dele aye, ọdun yii lo si dẹni ọdun marundinlọgọta loke eepẹ.
O kawe nileewe ẹkọṣẹ tiṣa kan, Local Authority Teachers College Demonstration School, eyi to wa niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, laarin ọdun 1973 si 1979, lẹyin naa lo lọ sileewe girama, St. Charles Grammar School, to wa niluu Oṣogbo, lọdun 1979 si 1984.
Laarin ọdun 1984 si 1986 lo kawe ni Poli ibadan, iyẹn The Polytechnic, Ibadan, o si gba sabukeeti onipo giga West African School Certificate (Advanced Level).
Sabukeeti yii lo fi tọwọ bọwe p’oun fẹẹ ṣiṣẹ ṣọja lọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1987, gẹgẹ bii ọkan lara awọn awọn ọmọ ẹkọṣẹ ologun tuntun ti 39th Regular Course, nileewe ẹkọṣẹ ologun Nigerian Defense Academy, to wa ni Kaduna.
Lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 1992, lo gba ipo 2 Lt nileeṣẹ ologun ilẹ wa, ẹka ti awọn ọjẹwẹwẹ, Nigeria Army Infantry Corps.
Lara awọn ẹkọ nipa iṣẹ ologun ti Lagbaja kawe gboye jade rẹ ni
a. Company Amphibious Operations Course – Amphibious Training School (May – June 1993). – C.
b. Young Officers’ Course (Infantry) – Nigerian Army School of Infantry, Jaji (September – December 1993). – C+
c. Basic Airborne Course – Nigerian Army School of Infantry Jaji (March – April 1995).
d. Advanced Airborne Course – Nigerian Army School of Infantry Jaji (November – December 1995).
e. Amphibious Staff Operations Course – Amphibious Training School (September – December 1997). – C
f. Company Commanders’ Course – Nigerian Army School of Infantry Jaji (February – May 2003). – C+
g. Battalion Commanders’ Course – Nigerian Army School of Infantry Jaji (September – December 2009). – B
h. Junior Staff Course – Armed Forces Command and Staff (May – December 2000). – C+
i. Senior Staff Course – Armed Forces Command and Staff (August 2005 – July 2006). – C+
j. Military Observers Course – Peacekeeping Wing Nigerian Army School of Infantry Jaji (February – May 2008). – B
k. ECOWAS Standby Force Battalion Command Post Course – Peacekeeping Centre, Bamako, Mali – (June – August 2010).
l. Strategy and Leadership Course – US Army War College (April 2003 – June 2014).
Ni ti iriri lẹnu iṣẹ, Ọga ṣọja tuntun yii ni wọn yan sipo Platoon commander
a. 93 Battalion – 1992 – 1995
b. 72 Special Forces Battalion – 1995 – 2001 as a Platoon commander.
Wọn da a pada si ileewe ologun Nigerian Defence Academy, lọdun 2001 si 2004 gẹgẹ bii olukọ wọn.
Lọdun 2004 yii lo kọja si olu ileeṣẹ ologun, iyẹn Army Headquarters Department, lẹka ti wọn ti n kọ ẹkọṣẹ ogun jija gidi (Army Training and Operations), oun atẹnikan ni wọn jọ n ṣakoso ibẹ.
Wọn tun ni ko sọda si Armed Forces Command and Staff College, loṣu Keje, ọdun 2005 si oṣu Keji, ọdun 2006, gẹgẹ bii oludanilẹkọọ awọn ologun. Ipo Litanaati Kọnẹẹli lo wa ninu iṣẹ ologun lawọn asiko yii.
Ibẹ lo wa ti wọn fi yan an sipo oludari awọn oṣiṣẹ ologun lati ọdun 2006 si 2009.
O bọ sipo igbakeji olori awọn oṣiṣẹ ologun lẹka akoso Deputy Chief of Staff (Administration) lọdun 2009 si 2012.
Ọdun 2012 si 2015 lo di kọmanda ikọ ologun 72 Special Forces Battalion Makurdi, ti wọn lọọ koju awọn agbesunmọmi l’Oke-Ọya. Ọdun 2015 lo di Birigedia Jẹnẹra ninu iṣẹ ologun.
O tun di olori awọn oṣiṣẹ ologun, Chief of Staff, ti Headquarters 8 Task Force Division, ni Monguno, laarin ọdun 2016 si 2017.
O bọ sipo Adele Alakooso iṣẹ ologun, Acting Director of Operations ni ẹka ẹkọṣẹ ati iṣẹ (Army Training and Operations) lolu-ileeṣẹ awọn ologun ilẹ wa, loṣu Kin-in-ni, lọdun 2018.
Wọn fi i ṣe Kọmanda Headquarters 9 Brigade, niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, loṣu Kejila, ọdun 2018, si oṣu Kẹrin, ọdun 2019. Ọdun yii lo gba irawọ Mejọ Jẹnẹra, bẹẹ lo si tun lọọ di iru ipo yii mu nipinlẹ Akwa Ibom, lọdun 2019 si 2020, ki wọn too fi i ṣe alakooso eto ẹkọṣẹ ologun.
Ọdun 2021 to tẹle e ni wọn yan an sipo GOC, iyẹn General Officer Commanding, ni olu ileeṣẹ awọn ologun ilẹ wa. Ipo naa lo si wa ti Aarẹ Bọla Tinubu fi yan sipo olori awọn ṣọja lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.