Monisọla Saka
Oṣerebinrin ilẹ wa nni, Ẹniọla Ajao, to ni sinnimọ ‘Ajakaju’, ti Idris Ọlarewaju Okunẹyẹ, ọkunrin to maa n mura bii obinrin tawọn eeyan mọ si Bobrisky, ṣe tori ẹ dero ẹwọn bayii ti ranṣẹ si i lọgba ẹwọn.
Lẹyin ti adajọ ti da Bobrisky lẹbi, ti wọn si ti ju u sẹwọn oṣu mẹfa, bi ko tilẹ yọju si kootu lasiko igbẹjọ naa, Ẹniọla ti gba ori ayelujara lọ lati kọ ọrọ ibanidaro ati imulọkanle ranṣẹ si Bobrisky.
Ninu ọrọ to kọ sibẹ lo ti ni, “Ẹyin eeyan mi. Pẹlu ọkan to wuwo ni mo fi n kan si yin lonii nipa iroyin to ba ni lọkan jẹ to ni i ṣe pẹlu Idris Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky. Ohun to ba ni lọkan jẹ gidi ni bo ṣe n la akoko iṣoro yii kọja.
“Mo fẹẹ fi ọrọ ibanikẹdun mi ṣọwọ si Bobrisky lasiko iṣoro yii. Ohun to lagbara ni keeyan maa wo o bo ṣe n dojukọ wahala yii, agaga pẹlu bo ṣe ni i ṣe pẹlu afihan sinnimọ ‘Ajakaju’.
“Ọna tawọn eeyan fi n yẹpẹrẹ Bobrisky, ti wọn n tabuku rẹ lori ẹrọ ayelujara, ko daa rara. Mo wa pẹlu rẹ ninu ẹmi, bẹẹ ni ọkan mi n ṣadura fun ọ, mo si lero pe yoo ri okun lati la akoko iṣoro yii ja.
“Gẹgẹ bii eeyan to mọ bo ṣe nira lati ma ṣe ni ominira, inu bi mi si bi idajọ ti wọn fun yin ṣe lagbara. O ṣoro lati gbagbọ pe eeyan ti ko ti i ko sinu wahala ri yoo maa dojukọ iru idajọ to le yii, lai si aaye fun owo itanran tabi beeli. Mo lero pe awọn igbimọ agbẹjọro Bobrisky yoo wa nnkan ṣe lati ṣe iranlọwọ fun un lori ẹ.
“Ọkan mi lọ sọdọ Bobrisky atawọn ololufẹ rẹ. Ẹ ma binu. Mo lero pe pẹlu agbara ọtun ni yoo fi jade kuro ninu eyi. Pẹlu ibanujẹ to ga, emi ni Ẹniọla Ajao”.
Bayii ni Ẹniọla kọ ọrọ yii si ojutaye.
O fẹrẹ ma si eeyan kan to pọn si ẹyin Ẹniọla.
Epe ni pupọ eeyan to ri nnkan to kọ yii si n gbe e ṣẹ.
Nigba tawọn kan n kun sinu lori idajọ ti wọn fun Bobrisky, ti wọn si n beere pe ṣe oun ni ẹni akọkọ ti yoo maa fọn owo lode ariya, tabi boya oun nikan lo nawo nibi ayẹyẹ Ẹniọla lọjọ naa ti wọn fi diju dajọ fun un, alabosi ati alakooba lawọn to pọ ju n pe Ẹniọla.
Wọn ni to ba jẹ ootọ ni lọọya Bobrisky sọ, ki lo mu un ti ko yọju si kootu lasiko ti wọn n dajọ Bobrisky, nigba to jẹ nitori fiimu rẹ lo fi ko si wahala, to waa jẹ ori ayelujara lo ti n ṣoju aye.
Wọn ni ko ma gbagbe pe awọọdu ọran to fun Bobrisky lojuna ati le ta fiimu ẹ lo ko ọkunrin bii obinrin yii sinu wahala to wa. Wọn ni Ẹniọla ko ba a tan, o tun daja silẹ laarin oun ati Portable olorin lori ayelujara, lẹyin to ṣe gbogbo eyi tan lo pa Bobrisky ti, to n tẹle ọkunrin olorin Zaazu Zeh naa kiri, lai bikita nipa ipo ti Bobrisky wa nigba naa.
Awọn kan tun bu u pe ki lo de to n ba Bobrisky sọrọ bii ọkunrin, abi oun yii kan naa kọ lo fun un ni ami-ẹyẹ to tọ sobinrin ni. Wọn ni ti wọn ba n wa aidaa inu eeyan, abanida-a ma-ba-ni- debẹ to fi Bobrisky pawo tan, to si da a da iṣoro to gbe ka a lori, Ẹniọla gangan ni ki wọn waa mu. Ati pe lori nnkan to ṣe yii, afaimọ ni ko ni i wa ọta pupọ funra ẹ.