Eyi niṣẹ ti oludije sipo gomina ẹgbẹ Labour ran si Tinubu

Faith Adebọla, Eko

Oludije funpo gomina ipinlẹ Eko, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party, Gbadebọ Rhodes-Vivour, ti ṣeleri pe gbogbo awọn tawọn janduku ṣakọlu si, ti wọn ṣe leṣe, tabi ti jijade wọn lọjọ idibo to waye kọja yii sọ dero ọsibitu lawọn maa ṣeranwọ owo fun, o lawọn maa san owo itọju iṣegun ti ọsibitu ba ni ki wọn san.

Bakan naa lo sọ pe ko sọrọ ninu ipe fun alaafia ati irẹpọ ti aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ-fibo-yan, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, pe laipẹ yii, pe ki eto wiwo ọgbẹ ọkan ti aawọ oṣelu da silẹ san bẹrẹ kaakiri awọn ipinlẹ, Gbadebọ ni ko le si iwosan ọgbẹ ọkan kankan ti idajọ ododo ko ba si, ko si le si ajọṣe alaafia nibi ti awọn eeyan ti wọn pa lara, ti wọn ṣakọlu si, ko ba ri itura ati idajọ ododo gba.

Nibi ipade pẹlu awọn oniroyin ti oludije naa ṣe lọsan-an Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta yii, lọfiisi rẹ to wa lagbegbe Lẹkki, lo ti sọrọ ọhun.

Ṣaaju ni Gbadebọ ti ṣabẹwo sawọn oṣibitu kaakiri, ti ọpọ awọn oludibo ti wọn ṣe leṣe lasiko idibo sipo gomina nipinlẹ Eko, eyi to waye lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii, ti n gba itọju lọwọ.

Ọkunrin ẹlẹyinju-aanu naa kede pe “Ọrọ ati ileri ta a ṣe pẹlu awọn olugbe Eko ni lati laaanu wọn, lati nifẹẹ wọn, lati pese ijọba rere ti gbogbo nnkan maa ṣe kedere si wọn, ti yoo si jihin iṣẹ iriju rẹ. Lanaa, mo ṣabẹwo sawọn ti awọn janduku ṣakọlu si, lati Abule-Ado de Surulere, Apapa ati Ikẹja. Mo ri awọn gende atawọn ọdọbinrin ti wọn yọ ọta ibọn lara wọn, ti wọn ṣa yannayanna, awọn to fapa da, fẹsẹ da, atawọn ti wọn ṣe leṣe gbogbo. A ti ṣi ikanni tuntun kan sori ẹrọ ayelujara ta a pe ni GRVcares2023, a si rọ gbogbo ẹyin tẹ ẹ ba ni adujukọ kan tabi omi-in latari akọlu ti wọn ṣe si yin lasiko idibo pe kẹ ẹ lọọ fẹjọ sun lori ikanni yẹn pẹlu ẹri, fọto yin, iwe-ẹri owo tẹ ẹ san lọsibitu, akọsilẹ ọlọpaa to fidi akọlu mulẹ, gbogbo owo tẹ ẹ ba na la maa san pada fun un yin lati ran yin lọwọ.

Niṣe lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ṣina bolẹ fawọn olugbe Eko lasiko idibo to kọja yii, bi wọn ṣe n gbe ẹbọ ni wọn n ṣaagun, wọn si fun awọn janduku laaye lati ṣe awọn eeyan leṣe daadaa, o waa ya tan, wọn lawọn n fẹ alaafia, lẹyin ti wọn ti kọwe si wahala.

Emi o lọrọ kan ti mo fẹẹ ba ẹgbẹ oṣelu imulẹ ti wọn ti sọ di awo sọ, awọn olugbe Eko ti wọn nifẹẹ si iṣejọba rere ni mo ba lọrọ. Ko ṣee ṣe pe ki eto ijọba demokiresi di tawọn agbero-kiresi mọ wa lọwọ l’Ekoo, nibi tawọn agbero yoo ti dọba le araalu lori, ti wọn yoo maa ṣe bii ologun kiri, bẹẹ la o si le jẹ ki wọn sọ Eko di ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo giro. A ri gbogbo bi wọn ṣe gbegi dina fawọn eeyan wa lati Ikoyi de Ikẹja, si Ikorodu. Wọn o le polongo ibo lori aṣeyọri ti wọn lawọn ni, ariwo ẹya kan lo l’Ekoo, ẹya kan fẹẹ gba Eko ni wọn n pa kiri. Nitori ki ẹni kan ṣoṣo le wọle ibo, wọn si ba gbogbo orukọ rere ti INEC ti ni lati ọdun mẹrin sẹyin jẹ. Nitori ẹyọ ẹni kan, oro ti wọn n ṣe loru tẹlẹ di ti ọsan gangan, wọn n rọjo epe ati eebu nitori Senetọ Bọla Tinubu ati awọn to ti ba a mulẹ. Eyi ti wọn ṣe kọja yii ki i ṣe ibo, jagidijagan, akọlu ati iṣera-ẹni-leṣe lo kun inu ẹ.”

Lẹyin eyi ni Gbadebọ parọwa sawọn mẹkunnu pe ki wọn sọrọ soke, ki wọn sọ bi nnkan ṣe ri lara wọn, o ni kawọn olugbe Eko tootọ ti wọn nifẹẹ igbe aye rere pariwo sita.

Ọkunrin naa tun ṣeleri pe awọn nigbẹkẹle kikun ninu ile-ẹjọ lati ri idajọ ododo gba. O loun gba pe Ọba adakẹ-dajọ ni Ọlọrun, gbogbo eru ati aitọ awa eeyan l’Ọlọrun ri, ti yoo si san kaluku lẹsan bo ti tọ.

Leave a Reply