Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lonii, ọjọ Iṣẹgun,lawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin bẹrẹ igbesẹ yiyọ Ọnarebu Agboọla Ajayi nipo gege bii igbakeji gomina ipinle Ondo.
Ki ilẹ ọjọ naa too mọ lawọn ọlọpaa atawọn ẹsọ alaabo mi-in ti duro wamuwamu si ẹnu ọna abawọle ọgba ile igbimọ ọhun ti wọn si n ṣayẹwo finnifinni fun ẹnikẹni to ba ti fẹẹ wọle.
Ayẹwo ti wọn ṣe fawọn aṣofin ọhun funra wọn kọja sisọ nitori pe olukuluku ni wọn pasẹ fun lati ṣafihan esi ayẹwo to sọ nipa ilera wọn lori arun Korona ki wọn too le wọle si gbọngan ibi ti wọn ti fẹẹ ṣepade.
Ki aago mọkanla ti wọn fi ijokoo si too lu lẹsẹ wọn ti pe wamuwamu ti wọn si n duro de asiko ti ipade yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu.
Akọwe ile igbimọ ọhun, Ọgbẹni Bọde Adeyẹlu, lo kọkọ ka awọn eto ti wọn fẹẹ ṣe lọjọ naa si etigbọ awọn aṣofin to wa ni ijokoo.
Abẹnugan ile, Bamidele Ọlẹyẹlogun, naa kin ọrọ akọwe lẹyin, o ni oun ti gbọ nipa awọn ẹsun ti wọn fi kan igbakeji gomina ọhun tẹlẹ.
Ọlẹyẹlogun ni igbesẹ tawọn n gbe ba ofin mu nitori pe ofin ro awọn aṣofin lagbara lati ṣewadii ẹsun ti wọn ba fi kan igbakeji gomina, bakan naa lo ni awọn tun lẹtọọ lati yọ ọ nipo lẹyin to ba ti jẹbi.
O ni niwọn igba ti wọn ti ri awọn asofin mẹrinla to bu ọwọ lu iwe iyọninipo naa, ohun to kan ni ki akọwe ile wa gbogbo ọna ti iwe yii yoo fi tete tẹ igbakeji gomina lọwọ.
Ẹwẹ, Ọlẹyẹlogun ko fun eyikeyi awọn aṣofin to jẹ alatilẹyin Agboọla laaye lati sọrọ pẹlu bi wọn ṣe gbiyanju to.
Kiakia lo pasẹ fun Ọnarebu Jamiu Maito to jẹ olori awọn ọmọ ile to pọ ju lati dabaa sisun ipade siwaju di Ọjọru, Wẹsidee ti i ọla.
Ninu awọn aṣofin mẹrindinlọgbọn, awọn mẹrinla ni wọn fọwọ si iwe iyọninipo naa, nigba tawọn mẹsan-an, ninu eyi ta a ti ri igbakeji abẹnugan, Irọju Ogundeji, olori ọmọ ile to pọ ju, Jamiu Maito ati olori awọn ọmọ ile to kere ju, Rasheed Ẹlẹgbẹlẹyẹ, ni wọn kọwọ bọwe tako o, nigba ti awọn mẹta yooku ko ti i sọ ibi ti wọn fi si ni tiwọn.
Kete ti wọn ti pari ijokoo lawọn aṣofin to jẹ alatilẹyin Agboọla raaye fẹhonu wọn han ti wọn si n pariwo pe ko bofin mu ki awọn mẹrinla ninu awọn mẹrindinlọgbọn yọ igbakeji gomina nipo.
Ninu ọrọ ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Idanre, Ọnarebu Festus Akingbasọ, ba awọn oniroyin sọ, o ni iwe ifitonileti saaju iyọninipo ti wọn fẹẹ fi sọwọ si igbakeji gomina ọhun jẹ ohun to lodi sofin nitori pe awọn to fọwọ si i ko to ida meji ninu ida mẹta ti ofin sọ.
Ọnarebu Samuel Ẹdamisan to n ṣoju awọn eeyan Irele ni o da oun loju pe ofo ọjọ keji ọja ni gbogbo igbesẹ iyọninipo ti wọn n gbe naa yoo pada ja si.
Aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ondo keji, Ọnarebu Adewale Williams, ni awọn kan lo n ti awọn aṣofin to fẹẹ yọ Agboọla ni itikuti.
Nigba to n sọ iha tirẹ lori isẹlẹ naa, Ọnarebu Olugbenga Ọmọle to jẹ agbẹnusọ ile ni ko sohun to lodi sofin rara ninu gbogbo eto tawọn ṣe lọjọ naa.
O ni ko pọn dandan ki awọn ti yoo fọwọ si iwe ifitonileti ko ida meji ninu mẹta, ida kan ninu mẹta lo ni o wa ninu alakalẹ ofin.
O ku ọla ti ijokoo awọn aṣofin naa fẹẹ waye ni Ọnarebu Agboọla ti mori le ile-ẹjọ giga kan l’Abuja, nibi to ti n rawọ ẹbẹ pe ki adajọ ka abẹnugan ile igbimọ aṣofin Ondo, Bamidele Ọlẹyẹlogun, lọwọ ko lori bi wọn ṣe fẹẹ yọ oun nipo.