Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọmọ iya kan naa mẹta ni wọn wa ninu awọn eeyan bii mejila to pade iku ojiji ninu ijamba ọkọ ajagbe simẹnti Dangote to waye niluu Akungba Akoko, lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja.
Inu ṣọọbu iya wọn to wa lẹgbẹẹ geeti Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu Akungba tawọn mẹtẹẹta wa lọkọ ajagbe ọhun ka wọn mọ, to si tẹ gbogbo wọn pa.
Meji ninu awọn ọmọ to ku ọhun la gbọ pe wọn jẹ akẹkọọ to wa nipele aṣekagba ni fasiti naa ki wọn too pade iku ojiji lalẹ ọjọ naa.
Iroyin iku wọn ni wọn ní iya wọn gbọ toun naa fi subu lulẹ, to si ku loju ẹsẹ.
Iṣẹlẹ yii lo mu kawọn alasẹ fasiti naa kede ṣisun idanwo awọn akẹkọọ to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii siwaju dọjọ mi-in ọjọ ire.