Ibo ijọba ibilẹ: Oludije ẹgbẹ APC wọle ni gbogbo ijọba ibilẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejilelogun (22), oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, lajọ eleto idibo ipinlẹ Kwara, iyẹn, Kwara State Independent Electoral Commission (KWASIEC), kede esi idibo ijọba ibilẹ to waye kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide.

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, iyẹn (APC), lo jawe olubori ninu gbogbo ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun (16) to wa ni ipinlẹ naa.

Amọ ṣa, ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ti fi aidunnu wọn han si esi idibo naa, wọn ni kikida aparutu ati magomago lo kun inu eto naa bamubamu.

Nigba to n kede esi idibo ọhun, Alaga ajọ KWASIEC, Mohammed Baba-Ọ̀kanla, ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bii eyi ti wọn ṣe pẹlu akoyawọ, ti wọn ko si fi ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan.

Ẹ̀wẹ̀, nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n fapa janu, ijọba ipinlẹ Kwara ti kira wọn kuu oriire lori esi idibo naa, ṣe ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn kede gẹgẹ bii ẹgbẹ to wọle idibo gbogbo ipo alaga kansu ipinlẹ yii naa lo n ṣejọba ipinlẹ naa ati orile-ede yii lọwọ.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Gomina ipinlẹ naa, Mallam Rafiu Ajakaye, fi sita lo ti ni awọn kọkọ dupẹ lọwọ awọn akọroyin fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lori bi eto idibo naa ṣe lọ nirọwọ-rọṣẹ, ati aṣeyọri eto idibo naa.

O tẹsiwaju pe ẹgbẹ oṣelu marun-un lo kopa ninu eto ọhun, awọn naa ni : APC, AMP, PDP, SDP ati ẹgbẹ Accord, o ni awọn dupẹ lọwọ gbogbo ẹgbẹ oṣelu naa patapata fun bi wọn ṣe gba alaafia laaye lasiko ati lẹyin idibo ọhun.

Leave a Reply