Faith Adebọla, Eko
Ko sẹni to reti iru nnkan bẹẹ, agbọ-diwọ-mọri ni iku ojiji to pa ilumọ-ọn-ka adẹrin-in poṣonu oṣere tiata ilẹ wa nni, Kunle Makinde Adetokunbọ, tawọn eeyan mọ si Dẹjọ Tunfulu.
Ọsibitu Jẹnẹra Ikorodu, lagbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko lọkunrin naa mi eemi ikẹyin si, loru ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, to kọja yii.
Ẹni ọdun mejilelaaadọta ni nigba tọlọjọ de, bo tilẹ jẹ pe o ku oṣu meji geere ki ọjọọbi ọdun kẹtalelaaadọta waye ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, tori ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 1969, ni wọn bi i.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti sinku Dẹjọ siluu Agbọwa, lagbegbe Ikorodu, lọjọ kan naa, nilana ẹsin Musulumi, sibẹ ọpọ eeyan lo ṣi n ṣe kayeefi nipa iru iku to pa a, ati ohun to ṣẹlẹ gan-an.
AKEDE AGBAYE ṣabẹwo sọdọ awọn mọlẹbi oloogbe naa, nile rẹ to wa l’Opopona Oduja, adugbo Ogunlẹwẹ, niluu Igbogbo, Ikorodu, lọjọ keji iṣẹlẹ yii, a si ba mẹta lara awọn ọmọ mẹrin ti Dẹjọ Tunfulu bi, sọrọ.
Pẹlu omije ni Tunji Adetokunbọ, toun ati baba rẹ jọ n gbe, fi ṣalaye pe ko si ami aarẹ kankan lara baba oun ṣaaju ọjọ iṣẹlẹ yii. O ni “Lọjọ Tusidee, wọn lọ sibi ayẹyẹ baidee Aṣiwaju Tinubu, lọjọ Wẹsidee, wọn lọ si lokeṣan kan lati lọọ ya fiimu, nigba to di alẹ, wọn paaki ọkọ ayọkẹlẹ wọn, wọn lawọn fẹẹ jẹ ẹja kan, wọn si gbe ọkada lọọ ra ẹja naa funra wọn, nigba ti wọn de, wọn lawọn funra awọn lo maa se ẹja yẹn bo ṣe wu awọn, wọn si wọ kiṣinni, wọn se e. Wọn ni amala lo wu awọn i jẹ, ka ba awọn ro amala, a si ro amala fun wọn, wọn jẹ ẹ, bi wọn si ṣe jẹun tan ni wọn lọọ sun.
Ọganjọ oru lọmọ kan to n sun sọdọ wọn waa kan ilẹkun yara mi pe ki n waa wo dadi mi, nigba ti mo de ọdọ wọn, mo ṣakiyesi pe wọn o le gbe apa, wọn o le gbe ẹsẹ. Mo beere ki lo ṣe wọn, wọn o le sọrọ, mo bi ọmọ to waa ji mi pe ki lo ṣẹlẹ, o loun naa o mọ, o ni boya tori ko si ounjẹ ninu wọn ni, tori wọn ti bi ounjẹ ti wọn jẹ lalẹ yẹn. Mo sare lọọ po ogi fun wọn, wọn si mu un, ṣugbọn ko fi bẹẹ siyatọ.
“Ba a ṣe gbe wọn lọ ọsibitu aladaani kan ti wọn maa n lo tẹlẹ niyẹn, awọn yẹn ni ko si nnkan tawọn le ṣe, ka tete maa gbe wọn lọ si jẹnẹra ni, la ba kọri sọna Jẹnẹra Ikorodu, nnkan bii aago mẹrin idaji ni, loru yẹn.
“Ni jẹnẹra, wọn fun wọn ni omi ati oogun diẹ, nigba tilẹ maa mọ, iyatọ diẹ wa, wọn ti n lokun pada, a ri i pe ẹgbẹ kan ara wọn ti ji pada, ṣugbọn ẹgbẹ keji ko ṣiṣẹ mọ, awọn kan ni boya arun rọpa-rọsẹ ni, a o tete mọ pe ẹjẹ ni ko to.
“Ṣa, wọn si fa ẹjẹ si wọn lara, wọn ni ẹjẹ o si lara wọn ni. Nigba ti wọn gba ẹjẹ kan tan, ara wọn ti bọ sipo, wọn wo oju mi, wọn ba mi sọrọ, wọn tiẹ n kilọ fun mi pe ki n ma ba awọn nọọsi yẹn ja, tori ara awọn ti ya, ṣugbọn ori ṣi n fọ awọn, mo si sọ fun wọn pe ki wọn tubọ rilaasi diẹ, pe dokita ni ẹfọri yẹn maa lọ laipẹ.
“Bi wọn ṣe n sinmi lọwọ, emi pada sinu mọto. Nigba ti mo pada lọọ wo wọn ni iṣẹju diẹ lẹyin igba yẹn, mọ yọju loju windo ni, mo ri i pe bi wọn ṣe n mi ti yatọ, wọn ti n mi gulegule, mo pe dokita to wa nibẹ sakiyesi pe mimi wọn ti yatọ kẹ, niṣe ni dokita yẹn ja’ju mọ mi pe ṣe emi ni mo fẹẹ kọ oun niṣẹ oun ni. O ni ẹjẹ keji ti wọn n fun wọn yẹn lo jẹ ki wọn maa mi bẹẹ, o ni ko sewu. Oju windo yẹn ni mo wa, tori wọn o ṣilẹkun mọ. Ọkan mi o balẹ, ṣugbọn mo saa kuro nibẹ, pe ki n pada waa wo wọn to ba ṣe diẹ.
“Nigba ti mo pada, mo ri i pe wọn o mi mọ, dokita kan n fọwọ tẹ wọn laya lasan ni. Mo pariwo mọ ọn pe ẹni yii ti ku kẹ! Mo ṣaa fi agidi wọnu ibẹ, mo gba ọwọ gbogbo wọn danu, mo bẹrẹ si i sunkun, pe dokita yẹn lo pa a, tori mo sọ fun un ki n too kuro pe baba mi o mi daadaa, o ni ko sewu, pe mi o le kọ oun niṣẹ oun. Bi dadi mi ṣe ku niyẹn.”
Adejọkẹ, ọmọ kẹta ti Dẹjọ bi, sọ nipa baba ẹ pe: “Bi gbogbo eeyan ṣe mọ wọn si alawada yẹn, bẹẹ naa ni wọn ṣe jẹ ninu ile, wọn maa n ṣawada gan-an. To ba si to asiko to yẹ ki wọn binu, wọn maa ba awa ọmọ wọn wi, ṣugbọn ibinu wọn o lọ titi, wọn maa da a sawada ni, wọn aa tun bẹ wa.
“Wọn gbiyanju gan-an, wọn gbiyanju gidi lori wa ni o. Eeyan to ba mọ Dẹjọ daadaa, aa mọ pe ko fọrọ awọn ọmọ ẹ ṣere rara, o sapa lori wa gidi ni.”