Eyi ni bi gbajumọ oṣere ilẹ wa, Iyabọ Oko, ṣe jade laye

Faith Adebọla

Iku alumuntu tun ti ja agba-ọjẹ lagboole tiata ilẹ wa gba, Abilekọ Kudirat Odukanwi, tọpọ eeyan mọ si Iyabọ Oko ti jade laye.

Aṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2023, ti i ṣe ọjọ ọdun Ileya gan-an ni mama agbalagba naa mi eemi ikẹyin lẹni ọdun mọkanlelọgọta (61).

Bo tilẹ jẹ pe pe ọpọ awuyewuye lo ti waye lori ilera irawọ oṣere yii tẹlẹ, latari bii aisan buruku kan ṣe da a gbalẹ lati ọpọ ọdun sẹyin, ti ko si ṣee ṣe fun un lati kopa ninu fiimu tabi lọ si oko ere mọ fun igba pipẹ, sibẹ, Ọlọrun lọra ẹmi obinrin naa, bi rumọọsi nipa iku rẹ ṣe n waye latẹyinwa lọrọ naa n ja si irọ.

Lowurọ ọjọ keji ọdun Ileya, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa yii, ni ọmọ oloogbe naa funra rẹ, Ọlamide, fi ikede iku mama rẹ yii lede lori ikanni ayelujara Fesibuuku rẹ, o ni iku ti ṣe bẹẹ pa mama oun loju de lalẹ ana. Ọmọ naa sọ pe aisan rọ-lapa-rọlẹsẹ kan lo ti da mama oun gbalẹ lati bii ọdun marun-un sẹyin, tawọn si ṣe gbogbo aajo ati itọju to yẹ fun un, bo tilẹ jẹ pe awọn ṣe ọrọ naa lalariwo rara.

Ọlamide ko sọ ju bẹẹ lọ, a o si ti i mọ hulẹhulẹ nipa bi iku yii ṣe waye gan-an ati ibi ti mama naa dakẹ si, bẹẹ ni wọn o ti i sọrọ nipa eto isinku rẹ, amọ ireti ni pe gẹgẹ bii ẹlẹsin Musulumi, eto isinku naa yoo ti waye.

Ọpọ awọn oṣere tiata atawọn ololufẹ Iyabọ Oko ni wọn ti n ṣedaro iku rẹ.

Folukẹ Daramọla, to gbe ọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun sori ikanni Instagiraamu rẹ lọjọ Tọsidee yii sọ pe:

“Haa, afigba ta a padanu rẹ, sun un re o, Iyabọ Oko, a ṣe gbogbo nnkan ta a le ṣe, amọ o ye Ọlọrun ju ẹda lọ,” bẹẹ lo fi awọn ami ati aworan ẹdun ọkan, omije ati ibanikẹdun sẹgbẹẹ ọrọ to kọ ọhun.

Leave a Reply