Monisọla Saka
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni awọn eean si n ba ọkan ninu aọn olori taka-sufee ilẹ wa, David Adeleke ti gbogbo eeyan mọ si Davido, daro iku akọbi ọmọ rẹ lọkunrin, Ifeanti Adeleke.
ALAROYE gbọ pe ọmọkunrin to doloogbe naa wa pẹlu Nani, iyẹn obinrin to n tọju rẹ. Lẹyin naa ni alase to maa n se ounjẹ fun wọn ninu ile naa waa daraaapọ mọ awọn mejeeji nibi ti ọn duro si.
Lasiko naa la gbọ pe Nani yii rọra yẹba kuro nibi ti wọn wa, to loọ gba ipe lori foonu rẹ.
Nigba to pada de, ko ri Ifeanyi nibi to fi i si, ṣugbọn niṣe loun ro pe o ti tẹle alase ti ọn jọ duro ko too lọọ gba ipe lori foonu ni.
A gbọ pe nigba to lọọ beere rẹ lọwọ alase yii niyẹn sọ fun un pe ọmọ naa ko si lodo oun, ni wọn ba bẹrẹ si i wa a kaakiri gbogbo inu ile naa. Fun odidi ogun iṣẹju ni wọn si fi wa a gẹgẹ bi aọn to sun mọ mọlẹbi naa ṣe sọ, ṣugbọn wọn ko ri i. Ọkan ninu awọn to n ṣọ ile naa lo ṣẹṣẹ waa ri ọmọ naa ninu omi iluwẹẹ to wa nile yii.
Ṣugbọn nnkan ti bajẹ kọja atunṣe, ọmo naa ti ku sinu oni yii, oku rẹ ni wọn gbe lọ sọsibitu. Oju-ẹsẹ naa ni dokita si ti sọ fun wọn pe ọmọ naa ti ku.
Alaroye gbọ pe Davido fara ya, niṣe lo si fa aṣọ ya mọ ara rẹ lọrun nigba ti wọn tufọ iku ọmọ rẹ fun un. Koda, o fẹẹ ja sita nibi ti iṣẹlẹ naa ba a lojiji, to si ka a lara de, niṣe ni wọn tete rọ ọ mu. Ọmọ to fi silẹ lai jẹ pe o n saisan, to waa jẹ pe oku rẹ ni wọn waa tufọ rẹ fun un.
Ile baba ọkunrin olorin naa ni wọn gbe oun ati iyawo rẹ lọ. Bẹẹ ni wọn ko gba ẹnikẹni laaye lati ṣabẹwo si wọn.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi iṣẹlẹ iku ọmọkunrin naa mulẹ. Bẹẹ lo fi ku un pe loootọ ni awọn pe mẹsan-an ninu awọn oṣiṣẹ to wa ninu ile naa fun ifọrọwerọ, ki wọn le waa tan imọlẹ si bi iṣẹlẹ naa ṣe ṣẹlẹ.