Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni ẹgbẹ oṣiṣẹ orileede yii, ‘Nigeria Labour Congress’ (NLC), ati ajọ ọlọja orileede yii, ‘Trade Union Congress’ (TUC), ẹka tipinlẹ Kwara, dara pọ mọ awọn ẹlẹgbẹ wọn kaakiri orileede yii, ti wọn si bẹrẹ iyansẹlodi gẹgẹ bii aṣẹ ti ṣe waa latọdọ awọn adari ẹgbẹ naa, latari pe ijọba apapọ ko dahun si awọn ibeere wọn.
Tẹ o ba gbagbe ṣaaju ni awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa NLC, ati ajọ ọlọja orileede yii, ‘Trade Union Congress’ (TUC), ti ṣekilọ fun ijọba pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ọba ati ti aladaani yoo bẹrẹ si i mọ iṣẹ loju tẹki, oloko ko ni i le roko, olodo ko si ni i le rodo, gbogbo ọna ọfiisi ati ileewe yoo da paroparo latari iyansẹlodi ọlọjọ gbọọrọ ti wọn kede pe awọn yoo gun le jake-jado orileede Naijiria, ti wọn si ni iyanṣẹlodi ọhun maa bẹrẹ lati ọganjọ oru ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii. Eyi ko sẹyin owo oṣu ti wọn n beere fun, ṣugbọn tijọba apapọ lawọn ko lagbara lati san.
Ni bayii, wọn ti waa mu ileri wọn ṣẹ nipinlẹ Kwara, gbogbo awọn ileeṣẹ ijọba, ileewe, ileefowopamọ to fi mọ awọn kootu ni wọn ti ilẹkun wọn pa, ti ko si oṣiṣẹ to le wọle tabi jade.
Owuyẹ kan sọ pe o ṣee se ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Kwara ṣepade pajawiri laarin ara wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu yii.