Monisọla Saka
Ifeanyi Adeleke, to jẹ ọmọ gbajugbaja olorin taka-sufee ilẹ wa, iyẹn David Adeleke, tawọn eeyan mọ si Davido ati ọrẹbinrin ẹ, Chioma Rowland, ti jade laye lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ọdun yii. Ifeanyi ni wọn lo ku sinu odo atọwọda (swimming pool) to wa ninu ile baba ẹ lagbegbe Banana Island, niluu Eko, nirọlẹ ọjọ Mọnnde.
Ọmọkunrin ọdun mẹta yii ni wọn lo ti pẹ ninu omi to ja bọ si ọhun ki wọn too kiyesi i pe o wa nibẹ. Loju-ẹsẹ naa ni wọn ti gbe e digbadigba lọ sile iwosan Lagoon Hospital, ṣugbọn ni kete ti wọn gbe e debẹ ni wọn sọ fun wọn pe oku ni wọn gbe wa. Boya lo pe ọsẹ meji lẹyin tọmọ naa ṣe ọjọ ibi ọdun mẹta ẹ logunjọ oṣu Kẹwaa, to kọja yii, to fi kagbako iku gbigbona ọhun.
Loootọ lo jẹ ọmọ kekere, ṣugbọn Ifeanyi o ṣajoji si swimming pool ni wiwẹ bo tilẹ jẹ pe o nilo amojuto. Ṣaaju akoko yii ni Davido ti maa n kọ ọmọ ẹ bi wọn ṣe n wẹ ninu omi adagun atọwọda naa. Ninu ọkan ninu awọn fidio to ti gbe sori ẹrọ ayelujara ri lọkunrin olorin naa ti n kọ ọmọ ẹ bi wọn ṣe n luwẹẹ ninu odo to wa ninu ile ẹ.
Logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2019, ni Davido ati Chioma bi Ifeanyi, wọn si ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mẹta ẹ lọna to larinrin ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin bayii.
Owuyẹ kan ṣalaye pe Davido ti rinrin ajo lọ sorilẹ-ede Amẹrika lasiko tiṣẹlẹ naa waye, Ibadan ni Chioma paapaa si wa, ọmọ ọdọ ni wọn ni wọn fi ọmọ ṣọ lasiko to re sinu omi, tẹnikẹni o si mọ titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ.
A oo ranti pe iru iṣẹlẹ bayii naa lo ṣẹlẹ si gbajumọ olorin asiko yii kan naa, iyẹn Dapọ Oyebanjọ, ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Dbanj ni nnkan bi ọdun meji sẹyin. Inu omi iwe to wa ninu ile awoṣifila to n gbe naa lọmọ ẹ ọkunrin kekere ko si tọmọ naa fi dero ọrun ọsan gangan.
Awọn gbajumọ oṣere, awọn olorin atawọn adẹrin-inpoṣonu bii AY Comedian, ti n ba Davido ṣedaro ọmọ ẹ to ku, wọn ni ki Ọlọrun rọ ẹbi naa loju.