Eyi ni bi wọn ṣẹ yinbọn pa oludije sipo kanselọ lo ku diẹ ki eto idibo waye l’Ogun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nigba tawọn ara ipinlẹ Ogun n mura lati jade lọọ dibo ijọba ibilẹ to waye kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindinlogun (16), oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii, iroyin ibanujẹ lawọn ara ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ji gbọ pẹlu bi awọn afẹmiṣofo ṣe yinbọn pa ọkan ninu awọn to n dije dupo kansilọ nijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, Ọnarebu Mutiu Akinbami.

Akinbami, ẹni tọpọ eeyan tun mọ si Egor, to ṣẹṣẹ fipo kansilọ silẹ ni ọkan ninu awọn wọọdu ijọba ibilẹ Ariwa Abẹokuta, ṣugbọn to tun n dupo naa fun saa keji, ni wọn yinbọn pa ni nnkan bii aago mẹfa aabọ irọlẹ ọjọ Ẹtì, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, faaji ni Egor n ṣe lọwọ pẹlu awọn ololufẹ ẹ, wọn n ta ayo, wọn si n fi nnkan mimu rẹ oungbẹ ninu ọgba ile ẹ to wa ni Line B3, Federal Housing Estate, laduugbo Olomore, nigboro ilu Abẹokuta, ti ipe kan fi wọle sori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, laimọ pe oniṣẹ iku lẹni naa to tẹ oun laago.

Ẹnikan to sun mọ oloogbe naa fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa pe ni kete ti wọn pari ipolongo idibo tan lọjọ naa, ti faaji n lọ lọwọ, ni kansilọ yii gba ipe kan lori ẹrọ ibanisọrọ rẹ, ohun to si sọ fun ẹni naa ni pe oun n bọ.

Bẹẹ lo da ọkada kan to n kọja lọ loju titi duro, ko fẹẹ gbe mọto lọ nitori idagiri sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ aarin igboro, ko mọ pe ẹnu iku loun n kanju lọ.

Bi oju ṣe n kan an lati lọọ pade ẹni to pe e to, ọmọkunrin rẹ ti ko ju ọmọọdun mẹfa lọ ko jẹ ko rimu mi, o ni dandan, afi bi oun tẹle e lọ. N lo ba kuku gbe ọmọ naa siwaju ẹ lori alupupu, o di igboro.

Iwadii akọroyin wa fidi ẹ mulẹ pe kansilọ yii ko ti i rin jinna pupọ, ko ti i de ibi ti wọn n pe ni iyana Bewery, nitosi Olómore, ti wọn fi pa a.

Wọn ni ọkọ Hilux kan lo deede dabuu ọkada rẹ niwaju, ti wọn si yinbọn fun un lagbari lẹyin ti wọn ti sun mọ ọn daadaa. Bo ṣe ṣubu lulẹ ni wọn tun sọ kalẹ ti i, ti wọn tun yinbọn fun un ni gbogbo ikun.

Lẹyin ti wọn ti ri i daju pe o ti ku patapata, awọn onígboyà apanijaye wọnyi tun lọ sibi oku ẹ, wọn mu ẹrọ ibanisọrọ to fi gba ipe wọn lọ, o si ku foonu kekere kan si i lọwọ. Lẹyin naa ni wọn fi oku kansilọ naa sinu agbara ẹjẹ nilẹ, ti wọn wa ọkọ wọn kuro nibẹ pẹlu ere asapajude.

Ẹni to ba akoroyin wa sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe, “Niṣe lọmọ ẹ pẹlu ọlọkada to gbe wọn, atawọn ọmọ igboro to wa laduugbo naa la ẹnu silẹ fun ibẹrubojo, wọn ko mọ ohun ti wọn le ṣe titi ti awọn ẹruuku naa fi sare ko sinu mọto wọn, ti wọn si sa lọ raurau.

“Ọpọ awa ta a jọ n gbe adugbo kan naa la fẹran rẹ nitori Egor jẹ ẹnikan to ma n ṣe daadaa sí gbogbo wa.”

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ pe iṣẹlẹ naa ko lọwọ oṣelu ninu rara gẹgẹ bii igbagbọ awọn eeyan kan, awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun lo yinbọn pa ọkunrin kansilọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn da nnkan boju ninu ọkọ ayọkẹlẹ Hilux alawọ funfun kan ti ko ni nọnba, ni wọn yinbọn pa a nirọlẹ ọjọ Jimọ.

Loju-ẹsẹ ti wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn eeyan wa leti lawọn ọlọpaa ti sare gbe ọkunrin naa lọ si Ijaiye General Hospital (Ileewosan ijọba ipinlẹ Ogun, to wa l’Abẹokuta). Ṣugbọn bi dokita ṣe yẹ ẹ wo ni wọn ri i pe o ti ku.

Iwọnba iwadii ta a ti ṣe fidi ẹ mulẹ pe, ogbontarigi l’Oloogbe Mutiu Akinbami, jẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n pe ni Ẹiyẹ, nileewe olukọni ijọba apapọ ti wọn n pe ni Federal College of Education, to wa laduugbo Òṣíẹ̀lẹ̀, niluu Abẹokuta, nitori ọkan ninu awọn ijoye ẹgbẹ ọhun lo jẹ nigba to wa nileewe yẹn.

“Amọ ṣa, a ti mu awọn kan ta a fura si lori iṣẹlẹ yii. Nigba ta a ba ṣaṣeyọri tan lori ọrọ yii, a o maa jẹ ki gbogbo araalu gbọ gbogbo bo ba ṣe jẹ nigba ti asiko ba to.

Tẹ o ba gbagbe, bayii naa lawọn ẹruuku lọọ ka ọkunrin ẹni ogoji ọdun (40) kan, Ọnarebu Adeleke Adeyinka, ẹni to n dupo kansilọ fun

Wọọdu kẹẹẹdogun, nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, mọ ibi ti oun atawọn alatilẹyin rẹ ti n ṣe faaji lọwọ, ti wọn si yinbọn pa a laduugbo Jide Jonnes, l’Ókè Ìléwó, niluu Abẹokuta.

Ahesọ ọrọ kan to ta si akọroyin ALAROYE leti, ṣugbọn ti a ko ti i fidi ẹ mulẹ ni pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Ọnarebu Adeyinka ti wọn yinbọn pa loṣu to kọja pẹlu Ọnarebu Akinbami ti wọn yinbọn pa lọjọ Jimọ yii, ṣugbọn ẹgbẹ ọtọọtọ ni wọn n ṣe.

Wọn ni awọn oludije dupo kansilọ mejeeji yii ni wọn jọ lọwọ ninu iku ara wọn nitori bi wọn ṣe yinbọn pa Akinbami ko ṣẹyin Adeyinka, ati pe ẹsan iku Adeyinka ni wọn gba ti wọn fi yinbọn pa ọkunrin ti wọn n pe bi Egor yii naa pẹlu.

Eeyan kan ti Ọlọrun ti figba kan ri ko yọ lọwọ iku ni wọn pe Egor ti wọn pa lọjọ idibo ku ọla yii. A gbọ pe wọn ti yinbọn mọ ọn lẹsẹ osi nigba kan ri, to jẹ pe gige ni wọn ge ẹsẹ naa, ti wọn si fi irin rọpo ibi ti wọn ge danu lara ẹsẹ yii.

Ibọn ti wọn yin fun un to mori bọ lọwọ iku nigba naa ni wọn pada waa fi pa a lọtẹ yii. Ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ẹgbẹ to n ṣejọba ipinlẹ Ogun lọwọ ni i ṣe ki wọn too yinbọn pa a bii ẹni pẹran nigbo ọdẹ.

Leave a Reply