Ọlawale Ajao, Ibadan
O kere tan, biliọnu lọna ọrinlelẹgbẹta o din meji (678b) lapapọ owo ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo na lọdun 2025 to n bọ yii.
Eyi ni iye owo to wa ninu akọsilẹ aba eto iṣuna, eyi ti Gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, gbe lọ siwaju awọn aṣofin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kọkanla, ọdun yii.
O han gbangba pe eto ẹkọ pẹlu awọn ohun amayedẹrun lo jẹ ijọba yii logun ju lọ, nitori awọn nnkan mejeeji wọnyi ni wọn yoo nawo le lori ju lọdun to n bọ lọna yii.
Gẹgẹ bii ìfọ́síwẹ́wẹ́ aba eto iṣuna ọhun, ìpèsè awọn ohun amayedẹrun lo wa nipo kin-in-ni, nitori owo to fi diẹ le ni biliọnu mejilelaaadọjọ Naira (₦152,265,859,738.19) nijọba yoo na lori oun nikan. Eyi si le ni ida mejilelogun (22) ninu ida ọgọrun-un apapọ owo aba eto isuna ọhun.
Nigba to n ṣalaye ọna ti yóò gbà nawo ọhún, Gomina Makinde sọ pe laipẹ yii loun fọwọ si biliọnu meji Naira lati fi ṣafikun ibi ti wọn ṣe atunṣe ọna onikilomita mejidinlaaadọta (48) to ti Ìdó lọ si agbagbe Ibarapa, ati pe kilomita mejila nijọba oun ti pinnu lati fi kun ibi ti wọn ti kọkọ gbe fun awọn agbaṣẹṣe lori atunṣe ọna naa.
Bakan naa lo fìdi ẹ mulẹ pe laipẹ yii nijọba oun yoo bẹrẹ atunṣe awọn oju titi to wa kaakiri inu igboro awọn ilu gbogbo nipinlẹ naa.
Eto ẹkọ lo wa nipo keji ninu bukaata ti ijọba ipinlẹ Ọyọ yoo fowo gbọ lọdun 2025.
Owo to le ni biliọnu marundinlọgọjọ Naira (₦ N145,354,783,399.80) ni wọn fẹẹ na lori eto ẹkọ, ọpọ ninu ẹ ni wọn yoo si fi ṣatunṣe si gbogbo ibi to bajẹ lawọn ileewe ijọba ipinlẹ naa gẹgẹ bi gomina ṣe fọwọ ẹ sọya niwaju awọn aṣofin.
Eyi yoo si jẹ afikun ṣí ileewe alakọọbẹrẹ marunlelọgọrun-un (105) ati ileewe girama bii ọgọrun-un ti ijọba rẹ ti tunṣe pẹlu atilẹyin ileefowopamọ agbaye.
Gomina Makinde ṣeleri pe gbogbo ere ti ijọba oun jẹ lori akitiyan rẹ lati mu igbelarugẹ ba eto ọrọ aje ipinlẹ yii loun yoo na lori awọn nnkan ti yoo ṣe gbogbo araalu lanfaani.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ẹ gba mi laaye lati gbe aba eto iṣuna ọdun 2025 yii, eyi ti yoo gbọ bukaata ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira (₦80,000) ta a ṣeleri lati maa fun awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bii owo-oṣu awọn to n gbowo to kere ju lọ ninu wọn.
“Inu mi yoo dun ti igbimọ ẹyin aṣofin wọnyi ba le fọwọsowọpọ pẹlu mi lati fọwọ si aba eto iṣuna yii fun aanfaani awọn ara ipinlẹ yii gẹgẹ bẹ ẹ ṣe maa n ṣe fun mi latẹyinwa’’.
Diẹ ninu awọn to peju pesẹ sibi eto naa ni Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Amofin Bayọ Lawal; igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Anbasadọ Taofeek Arapaja, to tun jẹ igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu Alaburada (PDP) fun ẹkun ilẹ Yoruba nibi; pẹlu Ẹnjinnia Jammid Gbadamọsi, ti oun naa jẹ igbakeji gomina ipinle Ọyọ nigba kan ri.
Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, funra rẹ lo lewaju awọn aṣofin yooku ti wọn gba gomina ati gbogbo awọn eeyan naa lalejo.