Adeoye Adewale
Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ọgbẹni Ayọdele Fayoṣe, ti sọ idi pataki toun atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kọọkan, awọn bii, gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Ọgbẹni Nysome Wike, ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ṣe wa lẹyin olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu gbagbaagba ninu ohun gbogbo to n ṣe.
Fayoṣe ni ko sohun meji to mu kawọn nifẹẹ aiṣẹtan si Tinubu ju pe o jẹ ẹni to loye kikun daadaa ninu eto iṣakoso ijọba to n lọ lọwọ yii.
Fayoṣe sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin lẹyin ipade pataki kan to waye laarin rẹ ati Aarẹ Tinubu niluu Abuja, l’Ọjọbọ, Toọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii.
Fayoṣe ni, ‘‘Ko sẹni ti ko mọ mi rara laarin ilu yii, orukọ mi ni Fayoṣe Ayọdele, mo wa lati waa fọrọ jomitoro ọrọ pẹlu Aarẹ Tinubu ni, oun ni ojulowo Aarẹ ilẹ wa lọwọ yii, inu mi si dun gidi lati waa ba a sọrọ lori ohun to han si mi daadaa, mo n fi akoko yii ki awọn eeyan orileede wa ku oriire, bi wọn ti ṣe yan Aarẹ Tinubu sipo pataki naa bayii, o si tun da mi loju daadaa pe Aarẹ Tinubu ni awọn ohun amuyẹ gbogbo lọwọ lati gbe iṣakooso ijọba orileede yii de ebute ayọ, laipẹ lẹ o mọ idi pataki ti mo ṣe n sọ awọn ohun ti mo n sọ wọnyi pe, olori to daa ni Tinubu.
Ohun kan ṣoṣo ti Aarẹ nilo lọwọ awọn ọmọ orileede yii ni pe ki wọn maa fadura ran an lọwọ nigba gbogbo, ki i ṣe iṣẹ kekere rara keeyan wa nipo olori orileede yii, onitọhun nilo adura gidi ni.
Mo si fẹẹ sọ fun yin pe ohun to mu ki emi, Wike ati Gomina Ṣeyi Makinde fi ṣatilẹyin gidi fun un ko ju pe a ri i pe o jẹ olori kan to loye kikun nipa iṣakooso ijọba orileede yii ni, ki i waa ṣe awa nikan lo ri awọn ohun amuyẹ to daa yii lara Tinubu, awọn kọọkan naa ri awọn apẹẹrẹ gidi yii lara rẹ, eyi la fi n sọ pe olori orileede wa yii jẹ olori to ni afojusun to daa nipa iṣakooso ijọba ilẹ wa ni gbogbo ọna bayii. A si tun ti pinnu pe Aarẹ Tinubu la maa ṣatilẹyin fun ninu ohun gbogbo, ko le ṣaṣeyọri ninu iṣakoso ijọba rẹ. Idi ree ti mo ṣe waa ki i ni ọfiisi rẹ l’Abuja.