Eyi ni idi ti awọn afọbajẹ ko ṣe ti i fi Ọlakulẹhin jẹ Olubadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Bi nnkan kan ba wa to n di awọn ọmọ Ibadan ati gbogbo olugbe ilu nla naa lọwọ lati ni ọba tuntun, ọrọ ẹjọ kan to wa ni kootu lo n fa ipenija naa, ko si ti i jọ pe ẹjọ naa yoo kuro ni kootu kiakia bayii pẹlu bi awọn afọbajẹ ṣe n ta ko ara wọn lori ọrọ naa.

Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja, lo gbẹjọ lọ si kootu, oun naa lo si lagbara lati gbe e kuro. Ṣugbọn iyapa ẹnu nla kan wa laarin oun atawọn afọbajẹ yooku ti wọn tun jọ jẹ igbimọ Olubadan. Eyi ni ko si le jẹ ki Olubadan tuntun gori itẹ bayii.

Ladọja lo faake kọri, o ni gbogbo awọn afọbajẹ yooku ti wọn ti n dade gẹgẹ bii ọba ni wọn gbọdọ kọkọ fọwọ siwee kan na ki oun too le gbe ẹjọ kuro ni kootu. Ṣugbọn ọpọ ninu awọn eeyan naa fariga, wọn ni awọn ko ni í fọwọ siwee kankan ni tawọn.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Ladọja, to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ, sọ pe oun gbọ pe awọn yooku oun n gbero lati ma ṣe jẹ ki oun jọba nigba ti ipo Olubadan ba kan oun, nitori naa loun ṣe pe wọn lẹjọ si kootu, nitori igbesẹ ti wọn n gbero lati gbe ọhun yoo kan fi ẹtọ oun dun oun lasan ni.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Jimọ, ọjọ keje, oṣu Keje, ọdun 2023, l’Olubadan ana, Ọba Mohood Lekan Balogun, pẹlu atilẹyin Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, fi awọn agba ijoye ilẹ Ibadan jọba, yatọ si Ladọja, ẹni to finnu findọ sọ pe oun ko jẹ iru ọba bẹẹ ni toun, Olubadan ilẹ Ibadan nikan loun fẹẹ jẹ.

Bẹẹ lawọn igbimọ Olubadan yooku di ọba alade, ti Ladọja nikan ko si kuro nipo agba Ijoye to ti wa latẹyin wa. Latigba naa lawọn yooku ti ri gomina tẹlẹ naa gẹgẹ bii ẹni to kere si wọn nipo, wọn gba pe awọn odidi ọba ilu ki i ṣẹgbẹ oun agba ijoye lasan.

Bo si tilẹ jẹ pe Ọtun Olubadan yii lo yẹ ko pe ipade gẹgẹ bii ẹni ti ipo rẹ ga ju lọ ninu igbimọ awọn afọbajẹ ilẹ Ibadan lọwọlọwọ bayii, sibẹsibẹ, nigba to pe wọn fun ipade lati yan Ọlakulẹhin gẹgẹ bii Olubadan tuntun, ko sẹni to da a lohun, wọn gba pe agba ijoye lasan loun, ko yẹ lẹni ti iba maa ranṣẹ pe awọn odidi ọba waa pade oun lori ọrọ ilu.

Ọtọ ni wọn kọkọ fa ọrọ yii laarin ara wọn ko too di pe wọn ri i yanju, ti wọn si lọ sibi ipade ti baba naa pe lẹẹkeji, lọjọ Jimọ, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun, 2024 yii, ti wọn fi yan Ọlakulẹhin gẹgẹ bii ẹni naa to kan bayii lati gori apere Olubadan.

Ni bayii ti wọn ti fi orukọ ọba tuntun naa ranṣẹ si ijọba, o yẹ ki ijọba fọwọ si i orukọ naa, ki wọn ṣeto ọjọ ti ọba tuntun yoo gba ọpa aṣẹ. Ṣugbọn ijọba ko le ṣe bẹẹ nitori ẹjọ to wa ni kootu. Nibi ti ọrọ tun ti kan Ladọja pẹlu awọn afọbajẹ yooku ree.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, awọn Mọgaji ilẹ Ibadan ṣabẹwo si Ladọja nile ẹ, ni Bodija, n’Ibadan, nibẹ lo ti sọ fun gbogbo aye pe oun ti ṣetan lati gbe ẹjọ kuro ni kootu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Emi atawọn igbimọ Olubadan yooku ti jọ n jokoo papọ, a si ti jọ n sọrọ papọ bayii. A ti gba lati gbe ẹjọ duro ni kootu.

“Mo gbọ pe awọn kan ti bẹrẹ si i fọwọ siwee. Lẹyin ti gbogbo wọn ba fọwọ siwee tan, nigba naa lemi paapaa yoo fọwọ si i, ta a si maa gbe ẹjọ kuro ni kootu”.

Lọjọ keji eyi, iyẹn Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lawọn igbimọ Olubadan ṣepade mi-in laafin Olubadan to wa l’Ọja’ba, nI’badan. Nibẹ lo si ti han gbangba pe eto lati jẹ Olubadan tuntun ko ti i le tẹsiwaju bayii, nitori awọn to kopa ninu ipade ọhun ko ṣetan lati fọwọ siwee ti Ladọja gbe ranṣẹ si wọn.

Lara awọn to kopa ninu ipade ọhun ni Osi Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Lateef Gbadamọsi Adebimpe; Ọba Abiọdun Kọla-Daisi (Aṣipa Olubadan); Ọba John Olubunmi Isioye-Dada (Ẹkẹrin Balogun); Ọba Kọla Adegbọla Aṣipa Balogun) ati Ọba Adebayọ Akande, ti i ṣe Ẹkarun-un Olubadan.

Nigba to n jabọ ipade ọhun fawọn oniroyin lorukọ awọn yooku, Osi Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Lateef Gbadamosi Adebimpe, ṣalaye pe, “nigba ti ede aiyede wa laarin wa la o fi gba ki Ọtun Olubadàn (Agba-Oye Ladọja) pe ipade, ta a sọ pe to ba pe ipade, a o ni i wa. O si pe ipade, a o sì lọ loootọ.

“Ṣugbọn nigba ti wọn waa sọ fun wa pe ofin eto oye jijẹ ọdun 1957 naa lo ṣi dè wa titi dasiko yii o, a ko le ṣe ohunkohun to ba tayọ ofin yẹn o, iyẹn lawa naa fi waa gba pe ko (Ladọja) pe ipade ni ibamu pẹlu ofin ọdun 1957.

“Ninu ipade yẹn la ti yan aṣaaju wa tuntun, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, gẹgẹ bii ẹni to maa jẹ Olubadan bayii. Iyẹn ni pe a ti tẹle ofin ọrọ oye jijẹ ọdun 1957. Gbogbo wa la ti gba bayii pe ofin ọdun 1957 la o maa lo.

“Ohun to ku bayii ni ki Agba-Oye Rashidi Adewọlu Ladọja lọọ gbe ẹjọ ti wọn pe si kootu kuro, ka le maa ba eto lati jọba lọ”.

Ṣaaju ni Ladọja ti kọkọ sọ pe awọn afọbajẹ yooku ni lati kọkọ fọwọ siwee pe awọn ko ni i gbe igbesẹ to le mu ki oun ma le jọba ko too di pe oun gbe ẹjọ ti oun pe wọn kuro ni kootu. Ṣe Balogun ilẹ Ibadan, Ọba Owolabi Ọlakulẹhin, ti ipo Olubadan kan bayii naa wa lara awọn ti baba naa pe lẹjọ.

Ṣugbọn Ọba Adebimpe gba pe ko nilo a-n-fọwọ-siwee kankan mọ, niwọn igba ti awọn ti fara mọ ofin oye jijẹ ọdun 1957, eyi ti Ladọja fara mọ, ṣugbọn ti awọn ti kọkọ kọyin si tẹlẹ, ko nilo ki ẹnikẹni tun maa fọwọ siwee nigba to jẹ pe ofin kan naa to n dari awọn ni gbogbo awọn jọ gbagbọ, ti awọn si jọ n lo bayii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “iyẹn ti kọja lọ. A ti ri i pe iwe ti wọn gbe wa yẹn, ko wulo mọ lasiko yii, nitori   gbogbo iwa ta a ti hu, gbogbo igbesẹ ta a ti gbe kọja lọ, o ti pa ọrọ pe a n fọwọ siwee rẹ. A ti fara mọ ofin oye ọdun 1957.  Iyẹn lo jẹ ka gba ki Ladọja maa pe ipade awa igbimọ Olubadan.

“Ṣe ẹ ri i pe ipade awa afọbajẹ ta a ṣe, gbogbo wa la jọ fọwọ siwee pe a fara mọ ki Ọba Olakulẹyin jẹ Olubadan. A si ti gbe iwe yẹn lọ sọdọ ijọba. Oun (Ladọja) lo ku to maa sọ pe oun naa ko ba wa ja mọ bayii, ka maa jẹ Olubadan wa lọ. Ofin oye jijẹ ọdun 1957 la fara mọ, ohun la a si maa ba lọ”.

Ninu ọrọ tiẹ, Aṣipa Olubadan, Ọba Abiọdun Kọla-Daisi, fi kun un pe, “bo ṣe ṣẹlẹ laye Gomina Ajimọbi naa ree, ti ọrọ ẹjọ to wa ni kootu ṣe idiwọ fun wa lati fi Olubadan jẹ. Nigba yẹn, Gomina Ajimọbi sọ pe oun ko ni i fọwọ si i ka jọba, afi ta a ba gbe ẹjọ ta a pe ijọba kuro ni kootu lo ku, nitori nigba yẹn, a pẹjọ ta ko idajọ ti wọn ti da sẹyin lori ọrọ oye Olubadan.

“Nigba ta a too gbe ẹjọ yẹn kuro ni kootu nijọba too gba ka fi Olubadan jẹ nigba yẹn. Iru ẹ naa lo tun n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii, ọna kan ṣoṣo to wa bayii naa ni ki ẹni to pẹjọ (Ladọja) gbe ẹjọ kuro ni kootu.

“Ko nilo ka tun ṣẹṣẹ maa fọwọ siwee kankan mọ, nitori gbogbo ohun ti wọn sọ pe ka ṣe ninu iwe yẹn patapata, gbogbo ohun ta a ti ṣe sẹyin ni”.

Nibi ti nnkan de duro bayii, ọrọ iwe adehun ti Agba-Oye Ladọja n fẹ ki awọn afọbajẹ yooku fọwọ si, ṣugbọn ti awọn onitọhun kọ jalẹ, ni ko ti i le jẹ ki Ọlakulẹhin gori itẹ, nitori niwọn igba ti ẹjọ ọhun ba ṣi wa ni kootu, wọn ko ni i le gbe ade ati ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun.

Leave a Reply