Jọkẹ Amọri
Lati bomi pana ahesọ ti awọn kan n gbe kiri pe ija buruku n lọ laarin Gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ati Aṣiwaju Tinubu nitori bi ko ṣe ba awọn gomina ẹlẹgbẹ rẹ lọ sile ọkunrin naa nigba ti wọn lọọ ki i ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Alaga awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu, ti sọrọ.
Gomina naa to gba ẹnu Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlajide, sọrọ sọ pe ki awọn eeyan ma tẹti si ahesọ tawọn kan n sọ kiri pe nitori ija to wa laarin Gomina Kayọde Fayẹmi ati Aṣiwaju Tinubu ni ko ṣe darapọ mọ awọn gomina yooku lati lọọ ki i.
O ni awọn pẹlu Fayẹmi lawọn jọ wa nibi ipade awọn gomina ilẹ Yoruba to waye ni Marina, niluu Eko, lọjọ Iṣẹgun yii, ṣugbọn nitori pe Gomina Fayẹmi wa ninu awọn alejo pataki ti yoo ka apilẹkọ nibi ipade awọn agbẹjọro to n lọ lọwọ ni ilu Portharcourt, lo mu un tete fi ilu Eko silẹ, to si gba ibẹ lọ. Ki i ṣe pe nitori ija tabi wahala kankan wa laarin oun ati Aṣiwaju gẹgẹ bi awọn kan ṣe n gbe e kiri.
Tẹ o ba gbagbe, irọlẹ ọjọ Iṣẹgun lawọn gomina ipinlẹ Yoruba yii lọ sile Aṣiwaju Tinubu lati ki i lẹyin aiya ara to lọọ tọju niluu oyinbo.