Eyi ni ikilọ ti ileesẹ ọlọpaa fi lede lori eto idibo Satide

Faith Adebọla

Taago mejila ọganjọ oru to sami si ibẹrẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji yii, ba ti ro kango, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni gbedeke tijọba gbe kalẹ pe ko gbọdọ si lilọ bibi ọkọ lọjọ idibo yoo bẹrẹ iṣẹ, o si di aago mẹfa irọlẹ ọjọ Satide naa ki wọn too kasẹ ofin naa nilẹ.

Ọrọ yii wa ninu atẹjade kan ti Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin, fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji yii, eyi ti wọn fi ẹda rẹ sọwọ s’Alaroye, lorukọ Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa.

Ninu atẹjade naa, wọn ni keku ile gbọ ko sọ fun toko o, kadan o gbọ ko lọ ro foobẹ, wakati diẹ lo ku ka mu ọjọ ti gbogbo ọmọ orileede yii ti n foju sọna fun lati bẹrẹ eto idibo, iyẹn Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ti eto idibo sipo aarẹ, ati ti awọn aṣọfin agba, iyẹn awọn sẹnetọ, ati tawọn aṣoju-ṣofin l’Abuja, yoo waye.

Latari eyi, ko ni i saaye fun igbokegbodo irinna eyikeyii, ibaa jẹ eyi to n rin loju titi, baaluu to n fo loju ofurufu, ati ọkọ oju-omi. Wọn ni lati aago mejila oru naa titi daago mẹfa ni ofin naa yoo fi mulẹ.

Amọ ṣa o, awọn ọkọ ti iṣẹ wọn jẹ akanṣe, to si jẹ iṣẹ aigbọdọmaṣẹ, bii ọkọ agbokuu-gbalaaye, iyẹn ambulansi, ọkọ ọlọpaa ati tawọn agbofinro yooku torukọ wọn wa lakọọlẹ ijọba bii tawọn ṣọja, Sifu Difẹnsi ati ẹṣọ Nẹbọhuudu le maa ba iṣẹ wọn lọ tori iṣẹ wọn pọn dandan lasiko idibo.

Bakan naa ni wọn fawọn ọkọ ileeṣẹ panapana, titi kan tawọn oniroyin lanfaani lati jade.

Bẹẹ ni wọn ni ko gbọdọ si fifọn feere yaafun-yaafun kankan laduugbo ati agbegbe ti eto idibo ba ti n lọ lọwọ, gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin eto idibo ilẹ wa tọdun 2022.

Wọn tun fi anfaani yii sin araalu ni gbẹrẹ ipakọ pe ki ọlọmọ kilọ fọmọ ẹ o, kidaa awọn ti wọn ba fẹẹ dibo ni ki wọn lọ sibi ti eto naa yoo ti waye, ki wọn si ṣe jẹẹjẹ lọhun-un, ko gbọdọ si ariwo tabi fa-a-ka-ja-a kankan, wọn ni kẹni to ba fẹẹ beere ohunkohun bi awọn oṣiṣẹ eleto idibo.

Nibubo idibo, wọn lofin faaye gba awọn araalu lati dibo, ki wọn si kọri sile wọn, tabi ki wọn duro lati ṣẹlẹrii kika ati iṣiro idibo nirọlẹ, amọ bi wọn ba maa duro, wọn gbọdọ ta kete bii ẹsẹ bata meloo kan si ibi ti idibo ti n lọ.
Wọn waa fọba le e pe ẹnikẹni ti ko ba fẹẹ jẹ iyan rẹ niṣu, ti ko si fẹẹ ri pipọn oju ijọba, ko ma ṣe tasẹ agẹrẹ si eyikeyii ofin to rọ mọ eto idibo. Wọn si fi awọn nọmba foonu kan lede tawọn araalu le fi ipe pajawiri ati atẹjiṣẹ sọwọ si, akiimọ bi wọn ba fura pe nnkan ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ nibikibi. Awọn nọmba ọhun ni: 08127155132, 08065154338, 08063299264, 08039344870.

Leave a Reply