Jọkẹ Amori
‘‘Iriri nla to jinlẹ gidigidi, to si kun fun iyanu ni irianjo mi sidii oṣelu, mo si le sọ pe ẹkọ nla lo jẹ fun mi. Ọpọlọpọ nnkan ni mo ti kọ, bẹẹ ni n ko si kọ awọn ọpọ nnkan naa. Mi o kabaamọ rara pe mo pinnu lati dije fun ipo yii.
‘‘Mo wa n fi asiko yii dupẹ lọwọ ẹyin eeyan ipinlẹ Eko fun bi ẹ ṣe nigbagbọ ninu mi, ti ẹ si ṣe atilẹyin fun ipinnu mi lati dupo. Mo ri awọn ọkan-o-jọkan awọn atẹjiṣẹ ti ẹ fi n ranṣẹ si mi lori ayelujara atawọn eyi ti ki i ṣe lori ayelujara. Mo gbọ gbogbo ibi ti awọn eeyan to ṣatilẹyin fun mi kaakiri, ti wọn si n pe awọn to fẹẹ ba mi lorukọ jẹ nija.
‘‘Mo ranti awọn ọwọ ifẹ tẹ ẹ fi gba wa lawọn asiko ti a n polongo ibo ati igbagbọ ti ẹ ni ninu mi. Loootọ eto idibo yii le ma yọri si bi ti a fẹ, ṣugbọn igbesẹ to lọla la gbe, ni tododo, ija rere la si ja.
Bakan naa ni mo fẹẹ rọ ẹyin tẹ ẹ ni ero rere fun orileede yii ati ipinlẹ Eko pe ki ẹ ma jẹ ki agara da yin. Mo ṣakiyesi pe ọpọ wa lo ti fẹẹ maa sọ ọkan nu lori bi ohun gbogbo ṣe ri. ‘‘Ṣugbọn ti a ba kọ ti a ko sọrọ, ko sẹni to maa gbọ ohun wa. Inu mi dun pe a tiẹ gbiyanju lati sọrọ soke.
‘‘Lẹẹkan si i, mo dupẹ lọwọ ẹyin ara Eko fun atilẹyin tẹ ẹ ṣe fun ọmọ yin. Bi mo ṣe n ṣepinu lori igbesẹ to kan lori ọrọ mi, n ko ni i jawọ lati mu ọrọ awọn araalu ni ọkunkundun, bẹẹ ni n ko ni i sọ ero ti mo ni lọkan lati jẹ agbẹnusọ fun awọn eeyan ilu nu.
Eko o ni i bajẹ o!
Bayii ni Funkẹ Akindele kọ ọrọ rẹ fun igba akọkọ leyin ti eto idibo ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta yii pari.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu PDP ni Funkẹ ti dije gẹgẹ bii igbakeji gomina. Ṣugbọn ipo kẹta ni ẹgbẹ wọn mu nigba ti esi idibo naa jade, Funkẹ ati Ọlajide Adeniran ti gbogbo eeyan mọ si Jandor ti wọn jọ dupo naa ni ibo ẹgbẹrun lọna mejilelọgọta ati diẹ (62, 445).
Babajide Sanwoolu to n ṣe gomina lọwọ ni ajọ eleto idibo kede pe o yege pẹlu ibo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (762, 134), nigba ti oludije ẹgbẹ Labour to wa ni ipo keji ni ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọọdunrun (312, 329).