Faith Adebọla
Bọla Ahmed Tinubu, olori orileede wa ti ki awọn ọmọ Naijiria kaabọ si ọdun tuntun, 2024, pẹlu awọn ileri lati ṣiṣẹ lori igba ọtun ati ọrọ-aje ti yoo mu igbaye-gbadun wọn sunwọn si lọdun naa.
Awọn ileri wọnyi lo wa ninu ọrọ akọsọ ti Tinubu ba awọn ọmọ orileede yii sọ laaarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ ki-in-ni, oṣu Ki-in-ni, ọdun 2024 yii.
O loun ba awọn ọmọ Naijiria yọ pe oju wọn ri ọdun tuntun, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ojo to ti rọ ti ilẹ ti fa mu lọdun 2023 to kogba sile.
Aarẹ ni oun mọ daadaa pe asiko yii ko rọgbọ tun tolori tẹlẹmu, o loun mọ inira ati aifararọ ti ọpọ awọn araalu n la kọja, nitori awọn igbesẹ ti iṣakoso oun ti gbe lori eto ọrọ-aje, paapaa latigba ti ijọba ti yọwọ kilanko rẹ ninu afikun iranwọ owo ori epo bẹntiroolu. “Mo ni oju ti mo fi n riran, ọkan mi si mọ bi inira naa ṣe ri lara.”
Sibẹ, Aarẹ ni ọjọ ọla Naijiria dara gan-an ati pe gbogbo inira pẹlu ipọnju asiko yii maa too di afisẹyin ti eegun alare n fi’ṣọ.
O ni: “Atunto nnkan le mu inira gidi wa loootọ, amọ ta a ba fẹẹ goke agba ka si jẹgbadun lọjọ-ọla, afi ka ṣe e. Ijọba mi n ṣe gbogbo nnkan ta a le ṣe lati din inira naa ku. Ẹ jẹ ki n sọ diẹ fun yin ninu awọn igbesẹ ta a fẹẹ gun le bayii, lati mu aye dẹrọ fawọn idile ati agboole gbogbo.”
Tinubu ni awọn ti jọọ fikun lukun pẹlu awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ gbogbo lojuna ṣiṣe afikun owo oṣu oṣiṣẹ, tori bẹẹ, fun oṣu mẹfa gbako, awọn oṣiṣẹ ti owo-oṣu wọn jẹ alabọọde yoo maa gba afikun ẹgbẹrun mẹẹẹdọgbọn naira lori owo-oṣu wọn.
Bakan naa lo ni oun atawọn alakooso ni ipinlẹ gbogbo ti ṣeto kan to pe ni Infrastructure Support Fund, eyi ti yoo pese owo fawọn ipinlẹ wọnyi lati pin fawọn araalu wọn ti ipọnju n ba finra.
Lẹsẹ kannaa, Bọla Tinubu ni eto fun ipese ounjẹ lọpọ yanturu ti n lọ bayii. Gbogbo awọn igberiko ati ibi tawọn agbẹ yoo ti le maa ṣiṣẹ oko wọn pẹlu nnkan elo igbalode ti yoo mu iṣẹ rọrun, ti yoo si mu ire oko wọn gberu lawọn n ṣiṣẹ le lori.
Aarẹ tun sọ pe dipo awọn ọkọ akero to n lo epo bẹntiroolu, awọn ọkọ ti yoo maa lo afẹfẹ, iyẹn gaasi la maa bẹrẹ si i ri kaakiri gbogbo ilu lati asiko yii lọ. O ni gbogbo irinajo oun siluu oyinbo ki i ṣe ti faaji rara, niṣe loun n ba awọn olokoowo sọrọ, ki wọn le waa daṣẹ silẹ, lati mu adinku ba airiṣẹṣe, ati ki okoowo le gberu daadaa.
Bẹẹ lo mẹnuba atunto to n lọ lọwọ ni banki ẹjalonibu ilẹ wa, iyẹn Central Bank of Nigeria, eyi ti yoo mu ki owo naira wa to n fojoojumọ dọbalẹ fun dọla le naro, ko si lokun si i.
Ni opin ọrọ rẹ, aarẹ dupẹ lọwọ awọn aṣofin apapọ, ẹka eto idajọ, ati awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ gbogbo, paapaa ẹgbe awọn oṣiṣẹ. O ni bi ki i ba ṣe igba gbogbo ni awọn jọ n fohun ṣọkan, sibẹ oun mọyi amọran wọn, ọmọọya loun si ka wọn si, toun si ṣe tan lati fun koowa lọwọ to tọ si i.