Ọlawale Ajao, Ibadan
Oludije funpo gomina nipinlẹ Ọyọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), nibi ibo gomina to waye lọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kẹta, ọdun yii, Sẹnetọ Tẹslim Fọlarin, ti sọ pe igbesẹ ti ẹgbẹ oṣelu oun gbe lati jẹ ki Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu jawe olubori ibo aarẹ to kọja lo jẹ ki oun padanu ibo gomina.
Lasiko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ APC sọrọ nibi ayẹyẹ ti wọn fi ṣami ijawe olubori Ọnarebu Rẹmi Abass Oseni, to n ṣoju ẹkun Ibarapa/Ido, nileegbimọ aṣoju-ṣofin, ni Sẹnetọ Fọlarin sọ pe oun ni wọn fi rubọ oṣelu.
Nigba to n ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bii ẹgbẹ to fẹsẹ rinlẹ ju nipinlẹ Ọyọ, Fọlarin sọ pe lẹyin ti awọn ri ipo sẹnetọ mẹta ati awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin mẹrinla mu ninu idibo aarẹ to waye ṣaaju, niṣe ni wọn fi ipo gomina ti oun n du ta ayo oṣelu.
O ni to ba jẹ oun naa ni, ipo aarẹ loun yoo ja fun, dipo ipo gomina, ati pe inu oun dun to jẹ pe latigba ti Tinubu ti di Aarẹ, awọn iṣẹ rere lo n ṣe, idi niyẹn toun ṣe n rọ awọn ọmọ Naijiria lati foriti i pẹlu ijọba Aarẹ Tinubu fungba diẹ si i, nitori wọn yoo gbadun iṣejọba rẹ laipẹ.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọnarebu Oseni, ẹni to dupẹ lọwọ awọn eeyan fun ifẹ ti wọn fi han si i, o si tun fi ọkan awọn eeyan balẹ pe Aarẹ Tinubu kunju oṣuwọn lati wa ojutuu si awọn iṣoro to n dojukọ ilẹ Naijiria.
Awọn igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Iyiọla Ọladokun ati Moses Alake; Shina Alabi, atawọn mi-in wa lara awọn ọtọkulu to wa nibi ayẹyẹ ọhun