Eyi nidi ti owo epo bẹntiroolu ko ṣe ni i wa silẹ lasiko yii – PENGASSAN

Adewale adeoye

Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ epo bẹntiroolu lorileede yii. ‘Petroleum And Natural Gas Senior Staff Association Of Nigeria’ (PENGASSAN) ti sọ pe ileeṣẹ ifọpo orileede yii to wa niluu Port Harcourt, ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu, ṣugbọn wọn ko ti i maa fọ epo bẹntiroolu jade nitori wọn n ṣe awọn atunṣe kan lọwọ ninu awọn ẹrọ ti wọn fi n fọ ọ. O ni kẹrosiini, iyẹn epo oyinbo, Diisu ati afẹfẹ idana nileeṣẹ ifọpo ọhun n ṣe jade bayii. O ṣalaye pe awọn ko ni i din iye tawọn n ta epo naa fawọn alagbata epo bẹntiroolu ku.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun sọrọ yii di mimọ fawọn oniroyin niluu Abuja, lẹyin ipade pataki kan to waye laarin awọn oloye ẹgbẹ naa lọjọ Iṣegun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ko si ani-ani kankan nibẹ mọ, ileeṣẹ ifọpo Port Harcourt ti bẹrẹ si i ṣiṣẹ ni pẹrẹu bayii, ṣugbọn eyi ko sọ pe ka din iye owo ta a n ta epo bẹntiroolu naa fun awọn alagbata epo bẹtiroolu ku, ko sohun meji to fa a ju bi owo Naira ilẹ wa ṣe n fojoojumọ ja wa silẹ lọja paṣipaarọ.

‘’Gẹgẹ bi mo ṣe sọ ṣaaju pe ileeṣẹ ifọpo Port Harcourt ti bẹrẹ iṣẹ, ka dupẹ gidi lọwọ awọn araalu bi wọn ṣe fungun mọ awọn alaṣẹ ijọba orileede yii kileeṣẹ ifọpo naa le bẹrẹ iṣẹ. Ki i ṣe gbogbo ohun tawọn alaṣẹ ijọba ba sọ la gbọdọ gba bẹẹ si wọn lẹnu. Awa paapaa gbọdọ foju wa ri ohun to n ṣẹlẹ. A lọọ ṣabẹwo sileeṣẹ ifọpo Port Harcourt fura wa, a si foju wa ri ohun to n ṣelẹ nibẹ. Iṣẹ ti rin jina nibẹ gidi, kẹrosiini iyẹn epo oyinbo, Diisu ati afẹfẹ idana nileeṣẹ ifọpo Port Harcourt naa n ṣe sita bayii, nitori awọn iṣẹ kọọkan ṣi wa ti wọn maa ṣe sara manṣiini to n ṣe epo bẹntiroolu sita ni wọn ko ṣe ti i bẹrẹ si i fọ epo bẹntiroolu.

Yatọ si eyi, oniruuru iṣẹ atunṣe ni wọn n ṣe sara ileeṣẹ ifọpo naa lọwọ bayii, inu wa si dun gidi fohun ta a foju wa ri nibẹ nigba ta a lọọ ṣayẹwo si i. Oke iṣoro kan gboogi ta a n koju ni bi owo Naira ilẹ wa ṣe n fojoojumọ ja wa silẹ, eyi maa ni ipalara fawọn ọja ta a ba n ṣe jade lorileede yii, fun idi eyi, ọwọngogo ṣi lawọn araalu yoo maa ra ọja epo bẹntiroolu naa bayii, ki i ṣe ni ẹdinwo rara.

Leave a Reply