Oniwaasu agba fun ijọ kan ti wọn n pe ni Trinity House, Lagos, Pastor Ituah Ighodalo, ti sọ pe loootọ ọrẹ oun timọtimọ ni Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu to n mura lati dupo aarẹ Naijiria, ṣugbọn o ni lae, fabada, ọkunrin naa ko le rọpo Aarẹ Buhari gẹgẹ bii olori orileede yii nitori awọn idi pataki kan.
Ighodalo sọrọ yii lasiko ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin kan ti wọn n pe ni Mediaroomhoob. O ni orileede Naijiria nilo eeyan to ṣetan lati ṣiṣẹ sin ilu, ki i ṣe ẹni to fẹẹ gba ipo aarẹ nitori pe o ti wa lọkan rẹ lati ṣe bẹẹ. ‘‘Ọrẹ mi timọtimọ ni Tinubu, emi gẹgẹ bii ẹnikan si nifẹẹ rẹ gidigidi, o ti ṣe daadaa si mi ri, eeyan daadaa ni. Ṣugbọn wiwa ni ipo adari lode oni kọja ohun ti o wu eeyan lọkan tabi ti eeyan ti n lepa tipẹtipẹ. Iru eeyan ta a fẹ ni ipo aarẹ ki i ṣe ẹni to n sọ pe o ti wa ninu ifẹ ọkan oun tipẹtipẹ lati di aarẹ, rara, o gbọdọ kọja iyẹn.
‘‘Kin ni awọn ohun to o ni fun ilu, kin ni awọn ohun to o fẹẹ ṣe fun ilu, ibo lo si n ko wọn lọ. Njẹ o ni ifẹ araalu lọkan, abi o kan ko awọn iwe-ẹri rẹ jọ lati kan di aarẹ lasan ni.
‘‘Ko si asiko fun iru nnkan bẹẹ yẹn mọ ni Naijiria, awọn eeyan ti wọn ṣetan lati sin Naijiria, ti wọn ṣetan lati fi ẹmi wọn silẹ fun awọn eeyan, awọn eeyan ti wọn ni iran fun Naijiria, ti wọn ni igboya lati gbe igbesẹ to yẹ, ti ki i ṣe pe wọn maa fi wa rubọ lagbo oṣelu nitori pe wọn fẹ nnkan kan tabi omi-in, ti wọn yoo waa tun da waa pada sẹyin, ti a oo si tun bẹrẹ si i jiya ni kosẹkosẹ lo yẹ nipo.’’
Ituah ni Aṣiwaju ti ṣe daadaa pẹlu awọn olori lọlọkan-o-jọkan to ti mu jade. O ni eyi ti yoo fi maa ronu pe oun fẹẹ di aarẹ, bi Naijiria yoo ṣẹ wa ni iṣọkan, ti wọn yoo si fẹnuko lati yan aṣaaju ti yoo mu itẹsiwaju ba orileede wa lo yẹ ki o maa ro.
‘‘Mo n foju sọna fun ọkunrin olododo to ṣetan lati fopin si iwa ibajẹ, ki i ṣe ẹni ti yoo kan maa bun awọn eeyan lowo, bi ko ṣe ẹni ti yoo maa fi kọ wọn lẹkọọ, ti yoo kọ ileewe, ileewosan, ti yoo si pese awọn ohun amayedẹrun.
‘‘Ohun to n mu orileede dagba ni ipese iṣẹ ti wọn ba n ṣe, iyẹn aapọn lati sọ awọn ohun eelo ta a ba ni di ohun ti a le lo. Bi iṣẹ ba wa, a o le pese oriṣiiriṣii nnkan to maa kari gbogbo ilu lati lo.’’
Bẹẹ ni Ighodalo sọ.