Adeoye Adewale
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gba beeli Ṣeun Kuti, iyẹn gbajumọ ọmọ olorin nni, Oloogbe Fẹla Anikulapo Kuti, wọn si n ba a ṣẹjọ pe o lu ọlọpaa, atawọn iwa ọdaran kan tileeṣẹ ọlọpaa orileede yii fi kan an lọwọ.
Mọnde, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun yii lo yẹ ki igbẹjọ ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an waye nile-ẹjọ Magisireeti kan to wa niluu Yaba, nipinlẹ Eko.
Eyi lo fa a ti ololufẹ rẹ gbogbo nilẹ yii ati ni igberiko fi peju si ile-ẹjọ yii, to fi mọ awọn oniroyin, lo peju si kootu naa, wọn fẹẹ mọ ibi ti ẹjọ naa n lọ. Ṣugbọn bi wọn ṣe n reti pe ki adajọ ti ẹjọ naa wa niwaju rẹ, Onidaajọ Adeọla Ọlatunbọsun, bọ sori aga lati maa gbọ ẹjọ ẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an lọ ni wọn kede pe adajọ agba ọhun ko si nile, wọn lo wa ni isinmi kekere kan.
ALAROYE gbọ pe Akọwe agba ile-ẹjọ naa, Ọgbẹni Babalọla, lo gba ẹnu adajọ ọhun sọrọ, to si sun igbẹjọ Ṣeun Kuti sọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni wọn sọ pe Ṣeun Kuti fọwọ lile kan mu ọkan lara awọn ọlọpaa orileede nipinlẹ Eko, nibi to ti n gba a eti ọlọpaa naa ṣere. Nigba to si maa fi dọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii kan naa, awọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu un, ti wọn si ju u satimọle wọn. Nnkan bii ọsẹ meji ni Ṣeun Kuti lo ninu atimọlẹ awọn ọlọpaa naa. Ti adajọ si gba beeli rẹ lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ti wọn bẹ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa.