Eyi tun ga o, ọlọpaa fipa b’ọmọ ọdun mẹrindinlogun sun lọfiisi rẹ   

Jamiu Abayọmi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Bẹnue ti fọwọ osi juwe ile fun konsitebu ọlọpaa kan, Belasa Iyangedue, to fipa ba ọmọ ọdun mẹrindinlogun laṣepọ lọfiisi rẹ.

Ọlọpaa yii ni wọn ni ko ti i lo ju oṣu mẹwaa lọ nidii iṣẹ agbofinro ko too ṣaṣemaṣe naa.

Ọmọdebinrin yii ni wọn lo wa lahaamọ ẹka olu ileeṣẹ ọlọpaa Tse Agbaragba, nijọba ibilẹ Konshisha, fẹsun ibanilorukọjẹ. Ọlọpaa yii lọọ parọ fun un pe oun fẹẹ ran an lọwọ lori wahala to gbe e de atimọle, lo ba tan an lọ sọfiisi kan. Nigba to mu un debẹ lo ba fipa ṣe ‘kinni’ fun un.

Ni kete t’ọlọpaa yii huwa laabi rẹ tan lọmọ yii lọọ fọrọ naa to DPO leti, ti wọn si lọọ fọwọ ofin gbe ọkunrin naa, leyii to jẹ ki wọn gbe ọrọ rẹ lọ solu ileeṣẹ ọlọpaa patapata niluu Makurdi, lẹka ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Bartholomew Onyeka, lo fidii iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa ti a wa yii, nibi to ti fidi ẹ mulẹ pe awọn ti gbaṣọ lọrun ọlọpaa naa, to si ti n jẹjọ ẹsun ifipabanilopọ ni kootu Majisireeti kan to wa ni Makurdi, nipinlẹ naa.

Leave a Reply