Eyi tun ga o, onikẹkẹ Marwa ti wọn ni ko gbe awọn ọmọ mẹrin lọ sileewe gbe wọn sa lọ

Adewale Adeoye

Ko sẹni to maa ri bi Ọgbẹni Chimaobi Agah, baba awọn ọmọ ileewe mẹrin kan tiyawo rẹ ni ki onikẹkẹ Marwa kan ba oun gbe awọn ọmọ naa lọ sileewe wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, to si poora pẹlu awọn ọmọ naa ṣe n ke, to n gbera ṣanlẹ nita gbangba, ti aanu rẹ ko ni i ṣeeyan,

Ninu fidio kan to wa nita bayii ni Ọgbẹni Agah to jẹ ọmọ ilu Ebonyi, ti sọ pe oun ko si nile lakooko ti iṣẹlẹ naa waye, nitori pe oun lọọ ṣiṣẹ niluu Enugu. Ṣugbọn oun gba ipe pajawiri kan latọdọ iyawo oun pe onikẹkẹ Marwa toun ni ko gbe awọn ọmọ mẹrin lọ sileewe wọn ti poora pẹlu awọn ọmọ oun.

ALAROYE gbọ pe agbegbe kan ti wọn n pe ni Umuaga-Ibeku, lẹgbẹẹ olu-ileeṣẹ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ Abia, ‘State Criminal Investigative Department’ (CID) lawọn tọkọ-taya naa n gbe, ati pe ọjọ ori awọn ọmọ naa ko ju ọdun mẹjọ, merin, ọdun kan aabọ ati ọdun kan lọ.

Ninu ọrọ ti baba awọn ọmọ ọhun n sọ lo ti ni, ‘‘Ẹbẹ kan ṣoso ti mo n bẹ gbogbo awọn araalu atawọn alaṣẹ ijoba ilu wa ni pe ki wọn ṣaanu mi, ki wọn ba mi wa awọn ọmọ mi mẹrẹẹrin jade laaye, gbogbo awọn ohun to yẹ ki n ṣe pata ni mo ti ṣe bayii, mi o ti i foju mi kan awọn ọmọ mi latigba ti wọn ti ji wọn gbe sa lọ. Mo ti lọ sileeṣẹ redio lati lọọ kede pe mo n wa awọn ọmọ mi gẹgẹ bi ohun tawọn ọlọpaa sọ fun mi pe ki n ṣe, orukọ mi ni Ọgbẹni Chimaobi Agah, lati ilu Amasiri, nipinlẹ Ebonyi.

‘‘Iṣẹ ni mo lọọ ṣe niluu Enugu, ibẹ ni mo wa tiyawo mi fi pe mi lori foonu pe oun ko ri awọn ọmọ mi toun ni ki onikẹkẹ Marwa kan b’oun gbe  lọ sileewe wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii. O ni nigba toun reti wọn pe ki wọn de lati ileewe ti wọn lọ toun ko ri wọn loun ba lọ sileewe wọn, ṣugbon awọn alaṣẹ ileewe naa sọ pe onikẹkẹ kankan ko gbe wọn wa sileewe naa rara, Lọjọ keji ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, ni mo pada de lati ibi ti mo lọ, ohun kan naa si lawọn alaṣẹ ileewe naa sọ fun mi. Loju-ẹsẹ ni mo gba ọdọ awọn ọlọpaa lọ, wọn fun mi ni ọlọpaa mẹrin lati lọọ wa awọn ọmọ naa, ṣugbọn a ko ri wọn titi tilẹ ọjọ naa fi ṣu. Awọn ọlọpaa yii kan naa ni wọn tun gba mi lamọran pe ki n lọọ ṣẹkede nileeṣẹ redio pe mo n wa ọmọ mẹrin. Gbogbo ohun ti wọn sọ pe ki n ṣe pata ni mo ti ṣe, ṣugbọn mi o ti i ri awọn ọmọ mi o’’.

Leave a Reply