Mo fẹẹ ya bara diẹ kuro lori eto ti a n ba bọ, ki n lo anfaani iku ọkan ninu awon aṣaaju wa, Oloye Ayọ Fasanmi, lati fi tun pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba si akiyesi pataki kan.
Kinni kan ṣẹlẹ ni 1965, ọpọ eeyan ko mọ kinni ọhun, awọn ti wọn ranti ẹ paapaa ko mọ itumọ ohun to jẹ. Lọjọ kẹjọ, osu kin-in-ni, ọdun naa, Ladoke Akintọla gbera lati Ibadan, o mu awọn eeyan diẹ dani. Awọn pataki to tẹle e lọjọ yii ni Rẹmi Fani-Kayọde, Ayo Roṣiji, Richard Akinjide ati Ọba Akran ti Badagry. Kaduna ni wọn kọkọ lọ, lọdọ Sardauna, nibẹ ni wọn si ba lọ si Ṣokoto, lọdọ Sultan igba naa. Ọjọ buruku lọjọ naa fun ilẹ Yoruba, ọjọ ti awọn eeyan wa yii ta ilẹ Yoruba fun awọn Fulani nitori ọrọ oṣelu ni. Lọjọ ti awọn Fulani ṣẹṣẹ gba pe loootọ, awọn ti jagun ṣẹgun ni Naijiria, awọn gan-an lawọn ni Naijria bayii, awọn Yoruba wa ni wọn si lo lati ṣẹgun, ati lati gba Naijiria. Akintọla ni aṣaaju wọn. Ko too digba naa, inu ijaya gidi lawọn eeyan yii wa. Ati Sultan ni o, ati Sardauan ni o, ati awọn ọmọ ẹgbẹ wọn gbogbo.
Awọn Fulani wọnyi bẹru awọn Ibo pupọ nigba naa, wọn bẹru Azikiwe, wọn lero pe wọn le gba Naijiria lọwọ awọn, paapaa lasiko ibo ti wọn yoo di ni 1964, ibo to jẹ akọkọ niyẹn nigba ti awọn oyinbo ti gbejọba silẹ fun wọn. Tẹlẹtẹlẹ, Awolọwọ atawọn ọmọ ẹyin rẹ ni ibẹru wọn. Ṣugbọn nigba ti wọn ti ri ẹgbẹ Action Group fọ si meji, ti wọn si ko ọpọlopọ awọn ọlọpọlọ nla nla ti Awolọwo fi ṣe aṣọ ibora, paapaa Akintọla ati Roṣiji, ti wọn si ti sọ Awolọwọ funra ẹ sẹwọn, wọn mọ pe ko si ohun ti Yoruba le ṣe mọ, nitori awọn ti gba agbara lọwọ wọn. Ṣugbọn gbogbo ọna ti wọn gba lati fọ aarin awọn Ibo, otubantẹ lo ja si, ko bọ si i fun wọn. Ohun to fa ibẹru ree, pe ti wọn ba fi le dibo ti awọn UPGA, iyẹn ẹgbẹ ti NCNC ati Action Group jọ n ṣe papọ, ba fi le wọle, nnkan yoo daru fawọn Hausa-Fulani atijọba wọn.
Ohun ti wọn fi fa Akintọla mọra ree: ti wọn fun un lowo, wọn fun un lọlọpaa, wọn fun un ni ṣọja. Nigbẹyin, bo tilẹ jẹ UPGA lawọn ò dibo mọ, Akintọla fi ẹgbẹ Dẹmọ rẹ ko ilẹ Yoruba sabẹ ẹgbẹ NPC to jẹ tawọn Hausa, ninu ajọṣepọ ti wọn jọ ṣe ti wọn pe ni NNA. Ṣugbọn lẹyin ti esi idibo ti jade tan lọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni 1965, Azikiwe ti i ṣe aarẹ Naijiria loun o gba, oun o ni i fa ijọba Naijiria le ẹgbẹ NPC tabi ẹni yoowu ti wọn ba fa kalẹ lọwọ. Ṣugbọn lẹyin ti wọn fi adajọ agba dẹru ba a, ti wọn fi ọga awọn oniṣegun oyinbo dẹru ba a, ti wọn mura lati sọ pe ori rẹ ti yi, o n ṣiwere diẹdiẹ, ki wọn le fi yọ ọ kuro nipo ẹ gẹgẹ bii aarẹ, Azikiwe sọrẹnda fun wọn, o ni oun ti gbọ, o si gba lati ṣebura fun Balewa ko maa pada waa ṣejọba. Gbogob ohun ti wọn ṣe yii pata, awọn ọmọ Yoruba lo jẹ ko ṣee ṣe.
Oniṣegun agba ti wọn fi dẹru ba Azikiwe, ti yoo sọ pe oun tẹẹsi ẹ, o larun ọpọlọ, Moses Adekoyejọ Majekodunmi ni. Awọn lọọya ti yoo rojọ pe ko bofin mu fẹni to yi lori lati maa ṣe ijọba lọ, Ayọ Roṣiji ati Fani Kayọde ni. Adajọ agba ti yoo gbọ ẹjọ pataki bẹẹ, adajọ Adetokunbọ Ademọla ni, nitori nibẹrẹ ọdun 1965, ko si ẹyọ lọọya kan tabi adajọ kan lati ilẹ Hausa, awọn Yoruba lo wa nidii eto idajọ. Ọkunrin to n dari eto yi labẹlẹ, to n fun awọn Hausa-Fulani yii ni awọn eelo ti wọn yoo lo fun ija naa, Akintọla funra rẹ ni. Bẹẹ lo jẹ gbogbo awọn eeyan ti wọn lo lati fi wọle ibo ni 1965 yii, Yoruba ni wọn. Nigba ti wọn si ti pari ibo, ti ọkan ti balẹ pe ijọba ti bọ si ọwọ awọn Hausa-Fulani yii pada, Akintọla ko awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ naa lẹyin, wọn gba Kaduna lọ lọdọ Sardauna Ahmadu Bello, wọn waa jọ lọ si Sokoto lati fara han niwaju Sultan, gẹgẹ bii aṣoju awọn to ṣee fọkan tan nilẹ Yoruba, wọn si mu un lọ sibi saare awọn Sultan to ti ku.
Ohun ti awọn Akintọla n ṣe ni gbogbo asiko yii, wọn ko ṣe e nitori ohun meji bi ko ṣe lati fi han Awolọwo pe agbara ti bọ lọwọ ẹ, awọn ti lagbara ju u lọ bayii, awọn si fẹ ko ye e pe awọn le fiya jẹ ẹ gbe ni Naijria ti ko sohun ti yoo ṣe. Ni gbogbo igba naa, wọn ti pa ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa rẹ, wọn ti da ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin silẹ, awọn yii kan naa ti wọn n ṣe oṣelu ati amofin, ti wọn si fi gbogbo ara koriira Awolọwọ, ni wọn wa ninu ẹgbẹ naa, ko sohun meji to ko wọn jọ bẹẹ ju ikoriira fun Awolọwọ lọ. Nigbẹyin, o han si gbogbo aye pe awọn ni wọn jẹbi, Awolọwọ lo jare wọn. Ṣugbọn ki ilẹ too pa oṣika, ohun rere yoo ti bajẹ, ki awon aṣaaju Yoruba yii too mọ pe ainiṣọkan ni wọn fi mu wọn, ohun rere nla ti bọ sọnu lọwọ wọn. Awọn ohun to bọ sọnu lọwọ Yoruba nigba naa, njẹ a ti i ri i gba pada bi! Nitori ẹ ni mo ṣe fẹ ka ronu wo, ka fi iku Fasanmi yii ṣe atẹgun nnkan tuntun fun Yoruba.
Mo woye nigba kan pe awọn ti wọn jẹ aburo wa ki i fẹẹ ba wa ṣe Afẹnifere, mo si beere ọrọ naa lọwọ aburo mi, ọga awọn ALAROYE, esi to fun mi ni pe ni toun, gbogbo ẹgbẹ to ba ti jẹ ti ọmọ Yoruba ni toun, nitori aṣoju ọmọ Yoruba ni iṣẹ iwe iroyin oun, yoo si ṣoro foun lati wa ninu ẹgbẹ kan ki oun pa awọn ẹgbẹ to ku ti. Nigba naa lo sọ ohun miiran to ya mi lẹnu. O ni ni ipari 1999, oun lọ si ile Baba Adesanya ti i ṣe aṣaaju gbogbo wa, oun ati Adebiyi, nibi ti oun ti ba baba sọrọ ni oun nikan pe ko ma ṣe aṣaaju ẹgbẹ Afẹnifẹre to n ṣe oṣelu, ẹgbẹ Afẹnifẹre to jẹ ti gbogbo Yoruba ni ko ṣe olori rẹ. O ni idi ti oun fi lọọ sọ bẹẹ ni pe ariwo igba naa ni pe Afẹnifẹre ni AD, oloṣelu Yoruba ti ko ba si ti si ninu AD ko le si ninu Afẹnifẹre. O ni oun ṣalaye idi ti eleyii ko fi le ri bẹẹ, oun sọ fun wọn pe ki Afẹnifẹre jẹ ti gbogbo ọmọ Yoruba, boya oloṣelu to wa ni AD, PDP, tabi ANPP, ki gbogbo wọn jade, ki wọn si ko ire oko wale fun Yoruba ni.
Alaroye ni ọrọ naa wọ baba yii leti, o si ni oun yoo ṣe nnkan si i. Ṣugbon lẹyin ti Adesanya ri awọn agbaagba to ku, esi ọrọ to jade ninu iwe iroyin ni bii ọjo kẹrin lẹyin ti Alaroye ni oun ri wọn ni “Afẹnifẹre is AD, AD is Afẹnifere”, O ni oun mọ pe esi ọrọ oun niyi. Lọjọ naa lawọn ti wọn jẹ PDP ati ANPP ninu ọmọ Yoruba ti bẹrẹ si i sa fun Afẹnifẹre titi ti AD paapaa fi fọ, ti Afẹnifẹre si tun da awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in silẹ ti ko yọri sibi kan. Ija yii kan naa lo fa a ti Fasanmi to ku yii fi di olori Afẹnifẹre apa kan, ti Baba Faṣọranti si jẹ olori Afẹnifẹre keji. Bi ẹ beere lọwọ awọn baba wọnyi, wọn yoo sọ fun yin pe ọkan naa ni Afenifẹre, ṣugbọn awọn naa jọ mọ lọkan ara wọn pe meji lawọn. Fasanmi ti waa ku bayii o, ko si ohun meji to si yẹ ki awọn agbaagba yii ṣe ju lati jade sira wọn lọ, ki wọn ba ara wọn sọrọ, ko ma si alaga meji fun Afẹnifẹre mọ. Bi Afẹnifẹre ba ti le ni alaga ẹyọ kan ati igbimọ ẹyọ kan, nibi ti iṣọkan Yoruba yoo ti bẹrẹ niyi.
Gbogbo akitiyan ti a n ṣe yii, gbogbo akọtunkọ iwe ti a n kọ sinu awọn iwe iroyin ati lori ẹrọ ayelujara pe Yoruba fẹẹ da duro. Nibo la fẹẹ duro si! Ori ilẹ wo la fẹẹ duro le lori! Ọna wo la fẹẹ gba de ori ilẹ naa bi ohun wa ko ba ṣọkan! Iṣọkan lo ṣaaju, bi ko ba ti si iṣọkan nilẹ Yoruba, bii igba ti a n yin agbado ṣeyin igba lasan ni. Iṣọkan lo sọnu laye awọn Akintọla ti wọn ta wa fun gambari, tabi nibo ni gbogbo ohun ti Awolọwo atawọn eeyan rẹ (pẹlu Akintọla naa) ṣiṣẹ fun laarin 1952 si 1966 nilẹ Yoruba wa loni-in, ṣebi gbogbo ẹ ni wọn ti gba lọwọ wa. Bii ti i ri fun iran tabi ẹya ti ko ba niṣọkan niyẹn. Ẹ jẹ ka lo iku Baba Fasanmi yii ka yi nnkan pada, bi bẹẹ kọ, a oo kan maa fi ori lu ogiri gbigbẹ lasan ni. Bi eeyan ba si fori lu ogiri gbigbẹ titi ti ko ba ṣiwọ, ori naa yoo bẹjẹ gbẹyin ni.
Eti yin meloo ẹyin Afẹnifẹre, ẹ jẹ ka kọkọ wa iṣọkan Yoruba, bi a ba ti ri iṣọkan Yoruba, gbogbo ohun to ku ni yoo to wa lọwọ lai ni i ṣe wahala rẹpẹtẹ.
Hmm . Eku owun o . Konibaje funyin
Olodumare yiofunwase. Amoran teminiwipe ki akun fun iwure fun osokan yi nile yoruba. Pelu egun buburu totiwa tele ki olodumare bawapa egunna run. Ki aleni agboye Latin arawa ati ife pelu ifowosowopo .ki abale segun awon olote tiwon n gbogun ti ile yoruba o. Olodumare afunwase o