Monisọla Saka
Baba agbalagba ilẹ Ibo to ti figba kan ṣe gomina ipinlẹ Anambra ri, Chukwuemeka Ezeife, ti fọwọ sọya pe ile-ẹjọ yoo wọgi le ikede ti ajọ INEC ṣe pe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lo jawe olubori ninu ibo aarẹ to waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.
Ezeife to ta ku jalẹ pe ibo ọhun lọwọ kan ojooro ninu, sọ pe o da oun loju ju ada lọ pe wọn o ni i bura wọle fun Tinubu, pẹlu bo ṣe jẹ pe wọn ti kede ẹ gẹgẹ bii aarẹ tuntun, ti ajọ eleto idibo, INEC, si ti fun un niwee-ẹri ‘mo yege’, lati fidi oriire rẹ mulẹ.
Ezeife to naka aleebu si ajọ INEC pe wọn ṣe magomago ninu eto idibo ọhun, ti wọn si tun fi si apa ọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije ẹgbẹ naa, Aṣiwaju Bọla Tinubu, sọ pe Tinubu ko le depo aarẹ.
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ yii sọ siwaju si i pe, ohun to foju han ni pe Peter Obi to jẹ oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party lo gbegba oroke jake-jado orilẹ-ede yii ninu ibo naa.
Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Awka, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Anambra, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun yii, Ezeife ni, “Gbogbo nnkan ti wọn ṣe yii lo jọ wa loju, to si ba wa lọkan jẹ, ṣugbọn a ko sọ ireti nu, nitori nigba tawọn eeyan ba fi maa to awọn ẹri lọlọkan-o-jọkan to ni i ṣe pẹlu igbesẹ ati eto yii jọ, nnkan maa ṣẹlẹ, gọngọ aa sọ, ironu yoo dori agba awọn eeyan kan kodo, a o si gba ẹtọ wa pada”.
Bakan naa lo tun sọ nibi ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun un lori tẹlifiṣan Arise TV, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, kan naa, o ni, “Eto idibo aarẹ to kọja yii ṣipaya oniruuru nnkan fawọn ọmọ Naijiria, mo si dupẹ lọwọ Ọlọrun fun iyẹn. Mo dupẹ lọwọ awọn orilẹ-ede agbaye ti wọn sọ ohun kan tabi omi-in lori ọrọ eto idibo yii, ti wọn si tun bu ẹnu atẹ lu gbogbo kudiẹ kudiẹ atawọn iwa magomago ti wọn dan wo nibẹ.
Koda inu mi ko dun pẹ ibo ti ẹgbẹ Labour Party ni lasiko eto idibo yii ki i ṣe eyi tawọn ajọ INEC kede ṣaa o. Loootọ ni, a mọ pe ayederu niyẹn. Ṣugbọn nnkan ta a ri ni pe ẹgbẹ Labour lo wọle nipinlẹ Eko, ati kaakiri orilẹ-ede yii”.
O ni, “Awọn kan ti wọn ko nigbagbọ ninu iṣọkan orilẹ-ede wa n ronu gba ibomi-in, amọ emi ti ri i bayii pe ọjọ iwaju ilẹ Naijiria ti n daa si i.
Emi ko nigbagbọ pe wọn yoo bura wọle fun Tinubu, koda pẹlu bo ṣe jẹ ọrẹ mi. Ti wọn ba ṣe bẹẹ, ajalu ati wahala buruku ni yoo di, amọ kinni yii ti la oju awọn ọmọ Naijiria. A dupẹ lọwọ awọn Yoruba, a mọ riri ipa takuntakun awọn Hausa, awọn ẹgbẹ atawọn ẹya gbogbo, fun bi wọn ṣe la wa loju yii. ”
Tẹ o ba gbagbe, laaarọ kutukutu Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Alaga ajọ INEC, Mahmood Yakubu, kede oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu ibo ọhun.