Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ilẹ England ti fagba han alatako wọn, Chelsea, ninu aṣekagba FA Cup to waye lonii pẹlu ami-ayo meji si ẹyọ kan.
Eyi ni igba kẹrinla ti Arsenal yoo gba ife-ẹyẹ idije yii, awọn lo si gba a ju ninu itan idije naa to bẹrẹ lọdun 1871.