Faith Adebọla
Bi wọn ba n ṣadura keeyan ma ri idaamu lọjọ alẹ rẹ, boya ni baba agbalagba ẹni ọdun mejilelọgọta (62) yii le ṣaamin o, tori ọkunrin naa ti ko ara ẹ sinu iyọnu ati aapọn gidi bayii, latari ẹsun ti wọn fi kan baba agbẹ, onijẹ amọdun ọhun pe niṣe lo ki ọmọbinrin aladuugbo rẹ kan mọlẹ nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keji, oṣu Kejila ta a wa yii, ọmọ ọhun ko si ju ọmọọdun meje pere lọ, lo ba fipa ba a laṣepọ, awọn agbofinro si ti mu un.
Ilu kan ti wọn n pe ni Aaaye Ọja-Ekiti, nijọba ibilẹ Mọba, nipinlẹ Ekiti, niṣẹlẹ buruku yii ti waye.
Nigba tọmọbinrin to wa nipele ẹkọ pamari tuu nileewe Saint John Anglican Primary School to wa laduugbo Ilegosi, l’Ọja-Ekiti yii n sọ bọrọ ọhun ṣe waye fawọn ọlọpaa lẹka ileeṣẹ wọn to wa niluu naa, o ni niṣe ni baba agbalagba tawọn eeyan tun maa n pe ni Baba Sebukky yii pe oun ati ẹgbọn oun ọkunrin pe kawọn waa jẹ irẹsi, o loun fẹẹ fun wọn ninu irẹsi toun ṣẹṣẹ se tan lọjọ naa.
Lẹnu eyi lọkunrin naa ba ran eyi ẹgbọn niṣẹ ọna jinjin, o fọgbọn tan aburo wọnu yara, lo ba bẹrẹ si i ṣerekere pẹlu rẹ.
“Ọmọbinrin naa ni, niṣe ni wọn gbe mi sori bẹẹdi wọn, wọn fọwọ bo mi lẹnu, ni wọn ba bọ pata nidii mi. Nigba ti wọn ki nnkan bọ idi mi ti ko wọle, ti ara si n ni mi, wọn mu ipara kan ninu kọbọọdu wọn, wọn fi pa ‘kinni’ wọn, ni wọn ba fipa ba mi laṣepọ.”
Ọmọbinrin naa ni oun n kigbe fun inira, amọ baba yii fẹju mọ oun pe oun ko gbọdọ pariwo, tori koun ma ba a ku.
Ninu alaye ti iya ọmọ naa, Abilekọ Funkẹ Awolọla, ṣe, o ni iṣẹ ile loun n ṣe lọwọ nirọlẹ ọjọ Satide naa, loun ba ri i pe ọmọ oun ọkunrin wọle laisi aburo rẹ obinrin pẹlu rẹ, nigba toun si beere pe nibo laburo ẹ wa, o lo wa lọdọ Baba Sebukky, nigba tọjọ si n bora toun ko ri i, loun ba tara ṣaṣa lọọ sibẹ, tori ẹgbẹ ile oun ni baba ọhun kuku n gbe, ko si n ṣe ajoji, amọ nigba toun debẹ, afurasi ọdaran naa kọ lati ṣilẹkun foun.
Iya ọmọbinrin yii ni: ọmọ mi ko kọkọ fẹẹ sọ ohun to ṣẹlẹ fun mi, amọ nigba to ya lo jẹwọ pe Baba agbaaya yii bọ pata nidi oun, o ṣe kinni foun, haa, ori mi daru wa ni! O lo kọkọ ki ika soun labẹ, lẹyin naa lo ti nnkan ọmọkunrin rẹ bọ ọ,” gẹgẹ bo ṣe wi.
Funkẹ ni awọn ti lọọ fẹjọ afurasi ọdaran oniṣekuṣe yii sun laafin ọba ilu naa, lẹyin eyi lawọn fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa ẹka Ọtun-Ekiti leti.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, SP Sunday Abutu ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti fi pampẹ ofin gbe Alagba Falana, awọn si ti n ṣewadii ijinlẹ lori ọrọ ọhun lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ State Criminal Investigation Department, SCID, to wa, ati pe lẹyin iwadii, ile-ẹjọ lawọn maa taari rẹ si laipẹ.