Fani-Kayọde balẹ sọsibitu, o lawọn ọtẹlẹmuyẹ lo fibeere po oun nifun pọ

Faith Adebọla

Ẹjọ hihuwa jibiti, ṣiṣe ayederu iwe ati fifi ootọ pamọ, eyi ti Oloye Fẹmi Fani-Kayọde n jẹ lọwọ ko le tẹsiwaju lọjọ Aje, Mọnde, ogunjọ, oṣu Keji yii, latari bi ko ṣee ṣe fun minisita feto igbokegbodo ọkọ ofurufu tẹlẹri naa ti i ṣe olujẹjọ lati wa si kootu, wọn ni idubulẹ aisan lọkunrin naa wa bayii, tori nigba ti yoo fi kuro lọdọ awọn ọlọpaa-inu apapọ ti wọn fibeere po o nifun pọ fọpọ wakati, ileewosan lo balẹ si, ti wọn n fun ni itọju.

Agbẹjọro Fani-Kayọde, Amofin Wale Balogun, lo taṣiiri ọrọ yii fun ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe nipinlẹ Eko, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, lasiko to yẹ ki igbẹjọ mi-in waye lori ẹjọ ti ajọ to n gbogun ti jibiti lilu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nni, EFCC, pe ta ko Fani-Kayọde.

Ẹsun mejila ọtọọtọ ni olujẹjọ naa n jẹjọ le lori, lara ẹ ni bi wọn ṣe sọ pe o yiwee, o ṣe ayederu iwe esi awọn dokita lori ilera ẹ fun Onidaajọ Daniel Osiagor, ti ile-ẹjọ giga apapọ kan l’Ekoo, nibi ti wọn ti bi i leere bo ṣe ṣe biliọnu marun-un Naira din diẹ (N4.9b) owo ijọba ti wọn lo poora mọ ọn lọwọ.

Lasiko to yẹ ki igbẹjọ naa tẹsiwaju ni Balogun sọ fun kootu pe onibaara oun, iyẹn Fani-Kayọde, ko le wa sile-ẹjọ, o ni boun ṣe n sọrọ lọwọ yii, ọsibitu kan ni olujẹjọ wa ti wọn ti n fẹ ẹ loju fẹ ẹ nimu, ti wọn n ṣaajo ẹ, latari ilera ẹ to mi sẹyin nigba ti yoo fi kuro lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ DSS, l’Abuja.

“Oluwa mi, ojoojumọ ni wọn ni ki onibaara mi maa yọju sawọn ni ọfiisi DSS, bo si tun ṣe wa nibẹ naa lawọn ọlọpaa tun ranṣẹ pe e, ti wọn fi ọkan-o-jọkan ibeere pa a lori latari awọn ọrọ kan to sọ ti wọn lo ju ẹnu ẹ lọ. Koda, bo ṣe kuro lakata wọn, ọsibitu lo balẹ si.

Latigba ti igbẹjọ ti waye kẹyin ni kọsitọma mi ko ti lalaafia, ọkan ẹ o balẹ, o si ti ṣakoba fun ilera ẹ. Ọsibitu la rọọṣi ẹ lọ lọjọ kẹrindinlogun oṣu yii, bo si ṣe kuro nibẹ, niṣe la tun da a pada si National Hospital, to wa l’Abuja.

Mo rọ yin, Oluwa mi, mo si rọ ile-ẹjọ, pe kẹ ẹ jọwọ, yọnda ọjọ kọkanlelogun ati ikejilelogun fun onibaara mi, k’ara ẹ le tubọ mokun, ko si le yanju ara ẹ lọdọ awọn DSS,” lọọya to ṣoju fun Fani-Kayọde lo bẹbẹ bẹẹ.

Ṣa, Onidaajọ Olubunmi Abikẹ-Fadipẹ ni oun sun igbẹjọ si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, amọ dandan ni ki olujẹjọ foju rinju pẹlu oun lọjọ naa.

Leave a Reply