Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ni awọn ṣi n wa awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn rẹ ara wọn danu bii ila lawọn agbegbe kan niluu Ilọrin, pẹlu bi wọn ṣe ṣeku pa gende-kunrin kan, Adelọdun Faruq, ti Agboole Ẹlẹ́ran, lagbegbe Ileefiimu, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Alukoro Ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, sọ fun akọroyin wa pe ni bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn awọn mọlẹbi oloogbe ko sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn fi sin oku ẹ nilana ẹṣin Musulumi, latari pe wọn ni oku Musulumi ki i pẹ nilẹ.
Adetoun tẹsiwaju pe pẹlu ohun ti awọn tọrọ naa ṣoju wọn wi ati ọna ti wọn gba pa gende-kunrin naa, o fihan pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn rodan ọwọ wọn, ṣugbọn iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mu awọn to wa nidii iṣeku pa ni ọhun.
Bakan naa lo sọ fawọn obi ati alagbatọ ki wọn kilọ fawọn ọmọ wọn ki wọn ma sọ ara wọn di irinṣẹ eṣu, ki wọn jinna si agbegbe ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti n rodan yii, tori pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo fimu kata ofin.
Adetoun tun rọ gbogbo olugbe ipinlẹ naa, paapaa ju lọ, awọn eeyan Ilọrin, lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo lati gbe igbesẹ kiakia, ki ọrọ a n rẹ ara ẹni danu bii ila yii le wa sopin. O ni ọlọpaa nikan ko le da a ṣe, ati pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ki i ṣe ẹmi airi, awujọ eeyan naa ni wọn n gbe, fun idi eyi, bi awọn eeyan ba ti kẹẹfin iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn maa fi to awọn ẹsọ alaabo leti.
Lara olugbe agbegbe naa to ba ALAROYE ṣọrọ sọ pe ẹnu lo ko ba Faruq, nitori pe ni kete ti awọn ẹruuku naa de, ti wọn si n tanna woju awọn araadugbo ni Faruq fi ohùn silẹ fun wọn pe ẹyin wo lẹ n tanna yẹn? Ta ni ẹ n wa? Eyi lo ṣokunfa bi wọn ṣe yinbọn lu u, to si ku loju-ẹṣẹ.