Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ to kọja yii, lọwọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, tẹ awọn mẹta yii, Jimoh Serifdeen, ẹni ọdun mọkandinlogun, Abdul Majid Saminu, ẹni ogun ọdun ati Usman Muhammed, ẹni ọdun mejidinlogun, lẹnu bode Naijiria si ilẹ Olominira Bẹnin, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, fẹsun ṣiṣe Fayawọ epo tawọn yooku si sa lọ.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ ṣifu difẹnsi nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, fi sita niluu Ilọrin, o ti sọ pe ajọ naa ti ri awọn afurasi onifayawọ epo mẹta mu, tawọn to ku wọn si na papa bora. Wọn tun ri galọọnu epo rọbi to to mẹtadinlogoje to kun fun epo gba lọwọ wọn ni ẹnubode Naijiria si ilẹ Olominira Bẹnin, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara. O tẹsiwaju pe ilẹ Olominira Bẹnin, ni wọn n ṣe fayawọ epo naa lọ lati ipinlẹ Kwara, wọn ni ileepo kan to n jẹ Wasmak niluu Kaima, ni wọn ti ko epo ọhun, ti ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi si ti ti ileepo naa pa.
Wọn ti wa ni akolo ajọ naa bayii.
Adari ajọ NSCDC, Ayinla Makinde, ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn afurasi to sa lọ lawari, ki wọn si foju awọn tọwọ tẹ ba ile-ẹjọ lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii.