Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti ti ṣebura fawọn kọmiṣanna mẹjọ ati oludamọran pataki meje tuntun.
Awọn kọmiṣanna naa ni: Amofin Akin Ọmọle (ẹka iroyin ati eto ọmọluabi), Dokita Oyebanji Filani (ilera), Ọgbẹni Akin Oyebọde (isuna ati idagbasoke ọrọ-aje), Ọmọọba Ọlabọde Adetoyi (eto ọgbin ati ipese ounjẹ), Ọtunba Ọladiran Adesua (ilegbee ati idagbasoke ilu), Ọmọwe Ọlabimpe Aderiye (eto ẹkọ, sayẹnsi ati imọ ẹrọ), Alhaja Mariam Ogunlade (ọrọ obinrin ati idagbasoke awujọ), Ọmọọbabinrin Iyabọde Fakunle-Okhiemen (eto ayika ati ohun alumọọni) ati Aarẹ Muyiwa Olumilua (idokoowo ati ileeṣẹ).
Awọn oludamọran pataki ni: Oloye Moji Fafure, Ọjọgbọn Francisca Aladejana, Ọgbẹni Foluṣọ Daramọla, Oloye Oluṣọga Davies, Oloye Fọlọrunṣọ Ọlabọde, Architect Tọpẹ Ogunlẹyẹ ati Ọgbẹni Ayọọla Owolabi.
Bakan naa ni Fayẹmi tun ya Ọjọgbọn Fẹmi Akinwunmi gẹgẹ bii alaga ẹka to n mojuto ileewe alakọọbẹrẹ (SUBEB) ati Ọgbẹni Fẹbiṣọla Adewale gẹgẹ bii ọmọ igbimọ alamoojuto ijọba ibilẹ.
Gomina naa waa kilọ fawọn to ṣẹṣẹ yan naa pe ki wọn ma ṣe imẹlẹ, bẹẹ ni ki wọn ma ronu owo ti wọn yoo ko sapo, bi ko ṣe lati ni erongba fun idagbasoke ilu.