Fayẹmi gbọdọ dupo aarẹ ni 2023 – Igbimọ lọbalọba Ekiti

Oluyinka Soyẹmi, Ado-Ekiti

 

Igbimọ lọbalọba Ekiti ti sọ pe awọn yoo gba gbogbo ọna lati jẹ ki Gomina Kayọde Fayẹmi fifẹ han si ipo aarẹ lọdun 2023, nitori awọn nnkan ribiribi ti yoo ṣe fun ilẹ Naijiria.

Eyi jẹ yọ ninu atẹjade kan latọwọ Oloye Olubunmi Ajibade to jẹ oludamọran lori eto iroyin fun Alawẹ tilu Ilawẹ-Ekiti, Ọba Adebanji Alabi, to tun jẹ Alaga igbimọ lọbalọba Ekiti.

Ọrọ naa ni igbimọ lọbalọba fọwọ si nibi ipade ti wọn ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lẹyin ti ikọ ẹlẹni-mẹrin kan ti wọn pe ara wọn ni ‘Our Belief Project’ gbe aba naa siwaju wọn. Ikọ naa, eyi ti Ọnarebu Alọba Abejide dari, ni wọn rọ awọn ọba naa lati sọ fun gomina ko tete ro ọrọ naa, ko si sọ erongba ẹ.

Awọn ọmọ ikọ ọhun to ku ni Alagba Akin Arẹgbẹ, Ọnarebu Mojisọla Fafure ati Ọjọgbọn Adio Fọlayan.

Nigba to n sọrọ lẹyin tawọn ọba kan ti sọ erongba wọn, ti wọn si gboriyin fun Fayẹmi, Ọba Alabi ṣalaye pe Fayẹmi yoo ṣe daadaa nipo aarẹ pẹlu bi nnkan ṣe ri lorilẹ-ede yii lọwọlọwọ. O ni Naijiria nilo ẹni to ṣi kere, to lokun ati agbara, to si jẹ ọlọpọlọ pipe bii gomina Ekiti.

O woye pe gomina naa wa lara awọn to ba ijọba ologun ja ki ijọba le bọ sọwọ alagbada, bẹẹ lo tun kawe gboye ọmọwe ninu imọ ogun jija, eyi ti yoo wulo fun ọrọ eto aabo to mẹhẹ nilẹ yii lọwọlọwọ.

Ọba Alabi sọ siwaju pe asiko ti to fun ọmọ Ekiti lati jẹ aarẹ nitori ipinlẹ naa ti ṣatilẹyin fawọn mi-in lati de ipo ọhun, bẹẹ lo ṣeleri pe gbogbo ọba ipinlẹ naa ni yoo ṣatilẹyin fun Fayẹmi.

Leave a Reply