Fayoṣe ki Tinubu ku oriire, o ni ki alaga PDP fipo silẹ

Ọrẹoluwa Adedeji

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, ti ki aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ku oriire yiyan ti wọn yan an sipo. Ninu ọrọ kan to gbe sori ikanni abẹyẹfo (twitter) rẹ, ni Fayoṣe ti ki gomina Eko tẹlẹ naa fun aṣeyọri rẹ lẹyin idibo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii.

Bakan naa lo rọ Alaga ẹgbẹ wọn, Iyorchia Ayu, pe ko fipo naa silẹ nitori ko mu ilọsiwaju kankan ba ẹgbẹ naa.

Fayọṣe ni, ‘‘Mo ki Tinubu ku oriire fun yiyan ti wọn yan an sipo gẹgẹ bii aarẹ Naijiria. Bi eto idibo ṣe wa to si ti lọ, mo fẹẹ rọ awọn oludije yooku, paapaa ju lọ Atiku Abubakar, pe ki wọn gba esi idibo naa nitori ifẹ orileede yii. Igba ati asiko mi-in yoo tun de.

‘‘Ṣugbọn ni ti alaga ẹgbẹ oṣelu wa, mo rọ ọ lati fi ipo naa silẹ kiakia, nitori ko mu itẹsiwaju kankan ba ẹgbẹ naa’’.

Bakan naa ni Olori ileegbimọ aṣofin agba, Ahmad Lawan, ti ki Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shetima, ku oriire bi wọn ṣe jawe olubori ninu ibo aarẹ naa. Ninu iwe ikinni ku oriire to kọ si i lo ti ni ijawe olubori yii fi igbagbọ ti awọn eeyan ni ninu ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije rẹ han.

Lawan ni, ‘‘Gbogbo awọn to dije dupo naa lo ja takuntakun lati de ipo ọhun, ṣugbọn eyi lo jẹ ki ijawe olubori wa dun jọjọ, adun yii yoo si pẹ titi laarin ẹgbẹ wa atawọn alatilẹyin wa kaakiri Naijiria, atawọn eeyan ti wọn nifẹẹ ijọba awa-ara-wa kaakiri agbaye’’.

O fi kun un pe bi awọn ṣe jawe olubori yii yoo jẹ ipenija fun awọn lati ṣiṣẹ takuntakun fun orileede wa gẹgẹ bii ẹni to nigbagbọ ninu ijọba onitẹsiwaju, ni ibamu pẹlu ilana ẹgbẹ awọn.      

Leave a Reply