Gbenga Amos, Ogun
Ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Felix Ikpeha, ti wa lakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ latari bi wọn ṣe ka pata obinrin mẹta mọ ọn lọwọ, ti ko si ri alaye to gunmọ kan ṣe nipa ibi to ti ri i, bẹẹ ki i ṣe pata lasan o, niṣe lẹjẹ rin awọn pata naa gindin.
Awọn ẹṣọ Amọtẹkun ni wọn mu afurasi ọdaran yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, laduugbo Imọ-Ayọ, nibi kan ti wọn n pe ni Ajibawo, niluu Atan-Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, nipinlẹ Ogun.
Ọga agba ẹṣọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, Alagba David Akinrẹmi, ni awọn aladuugbo naa ni wọn ṣakiyesi irin kọsẹkọsẹ tọkunrin yii n rin lọsan-an ọjọ naa, ni wọn ba fura si i, wọn si dọgbọn ta awọn ẹṣọ Amọtẹkun agbegbe naa lolobo.
Kia ni wọn ti de’bẹ, ni wọn ba bi i leere ibi to ti n bọ ati ibi to n lọ, ṣugbọn kami-kami lo n wi, eyi lo mu ki wọn bẹrẹ si i yẹ ara ẹ wo.
Iyalẹnu lo jẹ bi wọn ṣe ri pata obinrin mẹta tẹjẹ-tẹjẹ, wọn bi i leere ibi to ti ri wọn, o ni oun ṣa wọn nilẹ nibi toun ti n rin kiri ni, wọn si ni ko mu awọn de pato ibi to ti ri awọn ẹsibiiti ọran naa he, o loun o tiẹ mọbẹ mọ, ni wọn ba mu un.
Wọn lafaimọ ki afurasi ọdaran naa ma jẹ ọkan lara awọn afeeyan ṣetutu owo, wọn lo le jẹ awọn kan ni wọn ran an niṣẹkiṣẹ ọhun.
Ṣa, wọn ti fa jagunlabi le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii to lọọrin, wọn si ti ko awọn pata ẹlẹjẹ naa fun wọn. Abọ iwadii lo maa pinnu igbesẹ ofin to kan.