Festus ti wọn dajọ iku fun sa lẹwọn, lo ba tun lọọ jale l’Ogere

Gbenga Amos, Ogun

Ọgba ẹwọn White House, lọna Sapẹlẹ, nipinlẹ Benin, ni ọdaran to ti gbọjọ iku kan, Festus Okoeguare, wa, to n reti asiko ti wọn maa yẹgi fun un, ṣugbọn o yọ pọrọ sa lọ lasiko yanpọnyanrin iwọde EndSARS to kọja, bo si ṣe de ipinlẹ Ogun, niṣe lo tun lọọ ji waya ina ẹlẹntiriiki ka, lọwọ ba tẹ oun ati ekeji rẹ, Nancinant Paul Joshua.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ ta a wa yii.

Wọn ni olobo kan lo ta ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Ogere pe awọn afurasi ọdaran kan ti n ṣiṣẹ laabi nidii ẹrọ amunawa ati opo to gbe waya wọ agbegbe ti Fasiti Hallmark wa, nitosi ikorita ọna to lọ lati Ṣagamu si Benin.

Kia ni DPO Ogere ti ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi, pẹlu awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun to wa larọọwọto, ti wọn si lọ sibẹ, ṣugbọn bawọn kọlọransi ẹda yii ṣe foju gan-an-ni ọkọ ọlọpaa, niṣe ni wọn bẹ lugbo, wọn ṣina ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ko awọn waya ti wọn ji ge si, ni wọn ba sa lọ.

Amọ awọn ọlọpaa naa gba fi ya wọn, ọwọ si ba meji ninu awọn ole ọhun.

Nigba ti wọn wadii ọrọ wo lẹnu wọn ni teṣan, Festus jẹwọ pe ọgba ẹwọn White House, loun wa nigba ti lọgbọlọgbọ iwọde ta ko awọn ọlọpaa SARS fi waye lọdun 2020, latari idajọ iku tile-ẹjọ da foun fun ẹsun apaayan toun jẹbi rẹ. Asiko iwọde naa lawọn janduku kan fọ ọgba ẹwọn naa, oun si wa lara awọn ẹlẹwọn to jakun, loun ba sa wa sipinlẹ Ogun, ṣugbọn oun ko rikan ṣekan ju ole jija lọ, oun ati awọn ọrẹ oun kan lawọn jọ n ji waya ina ka, tawọn si n ta a lati rowo jẹun, idi gbewiri ọhun lọwọ ti tẹ oun yii.

Oyeyẹmi ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori awọn afurasi ọdaran mejeeji. Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni ki wọn wa awọn afurasi ole ti wọn sa lọ naa lawaakan, ki wọn le foju gbogbo wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Ni ti Festus, wọn lawọn maa fi i ṣọwọ si ọgba ẹwọn to ti jakun ni, ibẹ ni yoo ti gba sẹria ẹṣẹ rẹ lẹkun-unrẹrẹ.

Leave a Reply