Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Aarẹ tẹlẹ lorilẹ-ede yii, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ti gba gomina ti wọn tun fibo yan pada fun saa keji nipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, nimọran pe ko ri i daju pe aṣeyọri rẹ ninu idibo ọjọ Abamẹta,Satide, to kọja yii, eyi to ti fẹyin Osagie Ize Iyamu gbole, ṣe gbogbo ọmọ Naijiria loore.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii l’Ọbasanjọ sọrọ yii lasiko to n ki Obaseki ku oriire fun bo ṣe jawe olubori.
Baba naa tẹsiwaju pe esi ibo ọhun fi han gedegbe pe awọn ọmọ Naijiria mọ ohun ti wọn n fẹ ninu ijọba Dẹmokiresi asiko yii, iyẹn lo ṣe jẹ niṣe lawọn ara Edo duro ti ipinnu wọn, ti gbogbo eeyan si dunnu si abajade ibo naa.
‘O ti jawe olubori bayii na, mo rọ ọ lati nawọ oore ijọba awa-ara-wa si gbogbo ẹni to lọwọ si ijawe olubori rẹ, atawọn ti ko tiẹ dibo fun ọ pẹlu. Nitori gomina ipinlẹ Edo pata ni ọ, o ki i ṣe gomina awọn to dibo fun ọ nikan.
‘Nitori naa, ri i daju pe o ṣe gbogbo ohun to yẹ ko o ṣe. Mo nigbagbọ pe ifọkanbalẹ ilu yii ati idagbasoke tawọn ọmọ Naijiiria rere bii temi n fẹ yoo ti ọwọ rẹ wa. Mo gbadura pe ki Ọlọrun fun ọ ni ilera pipe ti wa aa fi ṣakoso ipinlẹ Edo fọdun mẹrin mi-in.’’ Bẹẹ l’Ọbasanjọ wi