Ọlawale Ajao, Ibadan
O ṣee ṣe ki fidio ihoho arẹwa ọkunrin kan bẹrẹ si i gba ori ẹrọ ayelujara kan bayii. Fidio ihoho ọhun ki i ṣe teeyan kan lasan, ti Yẹmi Ṣonde, ọkan ninu awọn agbohun-safẹfẹ to gbajugbaja lorile-ede yii, to tun jẹ oludasilẹ ileeṣẹ igbohun-safẹfẹ Yes FM ni.
Ṣonde, ẹni to ti figba kan jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn sọrọsọrọ ori redio ati tẹlifiṣan lorileede yii, Freelance and Independent Broadcasters Association of Nigeria (FIBAN), funra rẹ lo tu aṣiri ọrọ naa faye gbọ.
Irawọ agbohun-safẹfẹ yii, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Jigan Akala sọ pe lẹnu ọjọ mẹta yii lẹnikan ti oun ko mọ ri bẹrẹ si i pe oun lori foonu pe oun ni fidio ihoho oun Yẹmi Ṣonde kan lọwọ, ori ayelujara loun yoo si gbe fidio ọhun si bi oun Ṣonde ko ba tete fi owo ranṣẹ si oun kiakia, ati pe owo ti ẹni naa n beere bẹrẹ lati ori ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira (₦500,000) si miliọnu kan aabọ Naira (₦1,500,000).
O ni ihalẹ lasan loun pe ọrọ naa, afi nigba ti oun sọ pe ko fi ẹda fidio ọhun ranṣẹ si oun, ti onitọhun ṣe bẹẹ, ti oun si ri i pe fidio ibi ti oun ti bọra sihoho ninu yara oun ni loootọ.
Nibi ti ẹni naa pinnu lati yẹyẹ Ṣonde de, ALAROYE gbọ pe ẹni aimọ yii ti fi fidio buruku ọhun ranṣẹ si awọn eeyan pataki ti ọkunrin sọrọsọrọ naa mọ lati fi kinni ọhun gbowo lọwọ wọn.
Ṣugbọn ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Ṣonde sọ pe, “Mo mọ pe awọn alagbara lawujọ kan lo n lo ẹni naa lati ba mi lorukọ jẹ, o ni lati orileede Cote d’Ivoire loun ti n ba mi sọrọ, mo si ti sọ fun un pe to ba fẹẹ gbe fidio yẹn sori ẹrọ ayelujara, ko tete gbe e sibẹ, nitori mi o ni kọbọ kan ti mo maa fun un ninu owo ti mo fi oogun oju temi ṣiṣẹ fun”.
Jigan Akala, gẹgẹ bawọn ololufẹ ẹ ṣe maa n pe e, sọ pe oun ti ba agbẹjọro oun sọrọ lati gbe igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ naa, nitori amookunṣika ẹda ọhun ti pinnu lati mu oun balẹ ni gbogbo ọna.