Ọkan pataki ninu awọn ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho, ti gbogbo eeyan mọ si Igboho Òòṣà ti wọ̀lú lgangan, lbarapa, nipinlẹ Ọ̀yọ́, lẹ́yìn ọjọ meje to fun awọn darandaran ilu naa lati kuro nibẹ.
ALAROYE gbọ pe niṣe ni awọn Fulani darandaran naa kan lugbẹ nigba ti wọn gbọ pe okunrin naa ti wọ̀lú. Tefétefé lo si le gbogbo wọn danu.
Tẹ o ba gbagbe, fa-a-ka-ja-a ti wa laarin ọkunrin naa atijọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lori ìgbésẹ̀ to fẹ́ẹ́ gbe yii, ṣùgbọ́n okunrin naa ko bẹru, o yoju sílùú lgangan, o si le awọn Fulani darandaran kuro nibẹ.