Faith Adebọla
Fijilante lọkunrin ẹni ọgbọn ọdun kan, Lukuman Rasaki, lagbegbe Ijọra, nipinlẹ Eko. Adugbo ni wọn gba a fun pe ko maa ṣiṣẹ ọlọdẹ ilu, ṣugbọn akolo awọn ọtẹlẹmuyẹ lo wa bayii, latari bi wọn ṣe fẹsun kan an pe o yinbọn pa Musa Yahaya, ẹni ọdun mẹjindilọgbọn, o si pa a bii ejo aijẹ danu.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ṣalaye pe oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, niṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ọjọra, nipinlẹ Eko.
O ni ẹnu iṣẹ ṣiṣọ adugbo ti afurasi ọdaran naa n ṣe lo wa, ṣadeede lawọn aladuugbo gburoo ibọn to yin ni nnkan bii aago meji ọganjọ oru, wọn si gburoo bi oloogbe naa ṣe kigbe oro lẹyin tibọn ba a.
Adejọbi lawọn kan ni wọn tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago, lawọn agbofinro ti wọn n ṣe patiroolu ba sare de’bẹ, wọn ba oloogbe naa ninu agbara ẹjẹ, wọn si gbe e lọ sileewosan kan to wa nitosi, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, Musa ti ku patapata.
Nigba ti wọn bi Lukman leere bọrọ ṣe jẹ to fi yinbọn mọ ẹni ẹlẹni, o ni afurasi adigunjale loun ro pe o jẹ, tori ko tete da oun loun nigba toun pade ẹ, toun si bi i pe iru irin wo lo n rin kiri laajin, ko ma si lọ jẹ pe o maa kọkọ ṣe oun leṣe loun ṣe yinbọn fun un, bo tilẹ jẹ pe oun mọ pe igbaaya lọta ti maa ba a.
Boya o mọ tabi ko mọ, awọn ọlọpaa lawọn maa ba a ṣẹjọ apaayan. Wọn ti fi afurasi ọdaran naa ṣọwọ sawọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, o si ti n ran wọn lọwọ lẹnu iṣẹ iwadii wọn. Tiṣẹ iwadii ba pari, gẹgẹ bi Adejọbi ṣe wi, ile-ẹjọ lọrọ kan.